TOT vs CHE:Lampard tẹ ojú ọ̀gá rẹ̀ mọ́lẹ̀, ayò meji sodo ló kó lé Mourinho lọ́wọ́

Aworan Lampard

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ibi tagbalagba Jose Mourinho de duro,ọmọde Frank Lampard to figba kan jẹ akọnimọọgba fun ti ba pẹlu bi Chelse ti ṣe da bantẹ iya ayo meji sodo fun Tottenham rẹ.

Ifẹsẹwọnsẹ naa to jẹ akọkọ awọn mejeeji ni saa bọọlu yi gbona jọin jọin ti VAR si gbe Lampard ju Mourinho lọ.

Willian ni agbabọọlu Chelsea to jẹ goolu mejeeji fun Chelsea ni abala kini ifẹsẹwọnsẹ naa.

Tipa tikuku ni wọn fi yanju ipade naa

Ifẹsẹwọnsẹ naa kun fun ikọlu ohun gbigba ara ẹni ni nipa.

Lọdọ awọn agbabọọlu Tottenham, iwa yi ṣakoba fun aṣọle wọn ati Heung -min Son to gba kaadi pupa fun bi o ti ṣe gba Rudiger nipa.

Bayi,Son ti di agbabọọlu akọkọ ti wọn yoo fun ni kaadi pupa lẹẹmẹta ni saa bọọlu yi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ohun miran to ta abuku ba ifẹsẹwọnsẹ naa ni bi awọn alatilẹyin Tottenham kan ti ṣe n fi eebu eleyameya ranṣẹ si agbabọọlu Chelsea Rudiger.

Ẹmẹẹta ni wọn kede pe iwa idẹyẹsi yi n ṣe akoba fun ifẹsẹwọnsẹ naa.

Pẹlu abajade ifẹsẹwọnsẹ yi bayi, Chelsea ti ni ami mejilelgbọn ti wọn si wa ni ipo kẹrin lori afara.

Tottenham ni mẹrindinlọgbọn ti wọn si wa ni ipo keje.