Egúngún Arsenal tó kọ́kọ́ jó, ìran góòlù méjì ló padà wò lọ́wọ́ Chelsea

Aworan agbaboolu Chelsea ti wọn n yọ Image copyright Getty Images

Ọrọ naa ṣe awọn ololufẹ ẹgbẹ Arsenal bi ere ṣugbọn nigba ti adari ere yoo fọn fere, wọn ti fidirẹmi lọwọ Chelsea.

Goolu meji si ookan ni ikọ Frank Lampard fi tẹyin gberu Arsenal ni agboole wọn tii ṣe Emirates.

Pẹlu esi yi, Chelsea ti ni ami marundinlogoji ti wọn si wa ni ipo Kẹrin lori afara liigi Premiership.Arsenal wa ni ipo kejila

Pierre Emerick Aubameyang lo kọkọ jẹ goolu fun Arsenal ni abala kini ipade naa.

Ninu ẹgbẹ mejeeji,Arsenal lo pitu gidi gaan ni abala kini ti awọn ọmọ Frank Lampard ko si rojutu ara wọn .

Image copyright Getty Images

Ninu abala keji ni nnkan ti yi pada ti Chelsea si fi ina goolu meji jo Arsenal lara mọle.

Aṣiṣe lati ọwọ aṣọle Arsenal lo ṣokunfa goolu akọkọ ti Chelsea jẹ lati ọwọ Jorginho.

Tammy Abraham tojẹ atamatase Chelsea ti o ni goolu julọ ni saa bọọlu yi lo pari ijo pẹlu goolu ẹlẹkeeji ni iṣeju mẹ́tàdínláàdọ́rùn ún.

Bayi,ami mọkanla ni Chelsea yoo fi ṣagba Arsenal wọ ọdun 2020 lori afara liigi Premiership.

Related Topics