Serena Williams gba ife ẹ̀yẹ àkọ́kọ́ láàrin ọdún mẹ́ta sẹ́yìn

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Serena Williams na Jessica Pegula ni Auckland pẹlu 6-3; 6-4

Ife ẹyẹ akọkọ ni yii ti Serena Williams maa gba laarin ọdun mẹta.

O na Jessica Pegula ninu idije to waye ni Auckland pẹlu ami ayo Mẹfa si mẹta ati mẹfa si mẹrin.

Lati ọdun 2017 ti Serena Williams ti bi ọmọbinrin rẹ Alexis Olympia ni o ṣẹṣẹ gba ife ẹyẹ rẹ akọkọ.

Eyi ni ife ẹyẹ nla miran to tun gba lẹyin Grand Slam to gba ni Rome ni 2016 ati Australian Open to gba ni 2017 ko too bimọ.

Lẹyin idije yii ni oun ati ọrẹ rẹ Caroline Wozniacki ajọ dije ẹlẹni meji nibi ti wọn ti le jawe olubori ninu idije Auckland Tennis Center.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTrump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Awọn mejeeji a koju Asia Muhammed ati Taylor Townsend ninu idije naa lọjọ Aiku.

Oju Serena Williams to jẹ ẹni ọdun mejidinlogoji naa wa lara gbigba ife ẹyẹ Margaret Court 24 ti Australia to jẹ Grand Slam ẹlẹni kan ṣoṣo.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionEduardo: Mo ń jí mọ́tò pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi nítorí pé mo fẹ́ di 'Big boy'