Dangote vs Arsenal: Dangote lóun ṣì máa ra Arsenal ní 2021

Awọn agbabọọlu Arsenal ati Aliko Dangote Image copyright Twitter/Arsenal

Ọrọ gbajugbaja oniṣowo, Aliko Dangote ati rira ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal ti wa di igbin tẹnu mọ igi bayii.

Dangote to jẹ ẹni to lọrọ julọ nilẹ Afirika ti n sọ tipẹ pe oun nifẹ lati ra ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.

Gẹgẹ bi ololufẹ ikọ Arsenal fun ọjọ pipẹ, Dangote soju abẹ niko loni lori eto kan pe ọdun 2021 loun yoo ra Arsenal bayii.

Dangote ni kete ti oun ba ti kọ ile iṣẹ ifọ epo rọbi to tobi julọ lagbaaye ti oun n kọ lọwọ tan loun yoo ra Arsenal lọdun 2021.

Nnkan ko fara rọ laarin awọn ololufẹ Arsenal ati alaṣẹ ikọ agbabọọlu naa, Stan Kroenke lọwọlọwọ.

Tipẹ tipẹ lawọn ololufẹ Arsenal ti n sọ pe ki Ọgbẹni Kroenke ta ikọ agbabọọlu naa fun ẹlomiiran nitori wọn ko fẹran bi o ṣe n dari rẹ.

Ipo kẹwaa ni Arsenal wa lori tabili idije liigi ilẹ Gẹẹsi(Premier League), lẹyin ti Mikel Arteta di akọnimọọgba tuntun lẹyin ti Unai Emery kuro tan.

Ẹwẹ, ọpọ awọn ololufẹ Arsenal ni iroyin yii dun mọ, niṣe ni wọn n sọ loju opo ayelujara Twitter pe ki Dangote tete wa ra ẹgbẹ agbabọọlu naa.