AFCON 2021: Orílẹ̀-èdè Cameroon tí yóò gbàlejò ìdíje nàá yí ọjọ́ padà

Ami ẹyẹ idije AFCON Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oṣu Kẹfa ati Ikeje loyẹ ki idije naa waye, ṣugbọn Fecafoot sọ pe ayipada waye nitori bi oju ọjọ ṣe maa n ri ni akoko naa.

Cameroon Football Federation (Fecafoot) don announce say 2021 Africa Cup of Nations go happun for January 9.

Ajọ to n mojuto bọọlu afẹsẹgba ni Cameroon (Fecafoot) ti kede pe ọjọ kẹsan, oṣu Kinni ni idije Africa Cup of Nations yoo bẹrẹ l'ọdun 2021.

Oṣu Kẹfa ati Ikeje loyẹ ki idije naa waye, ṣugbọn ajọ Fecafoot sọ pe ayipada naa waye nitori bi oju ọjọ ṣe maa n ri ni orilẹ-ede naa ni akoko ti wọn n ṣe e.

Awọn alaṣẹ ajọ naa ṣe ipade pẹlu awọn aṣoju ajọ Confederation of African Football (CaF), to n mojuto bọọlu gbigba ni Africa l'Ọjọru nilu Yaounde.

"Ajọ Fecafoot fi si ori ayelujara pe "ọjọ kẹsan an, oṣu Kinni si ọjọ Kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2021 ni wsn yoo gba idije AFCON 2021".

Ayipada yii tun tumọ si pe idije naa ko ni i waye ni asiko kan na pẹlu idije Club World Cup ti yoo waye ni China l'oṣu Kẹfa, ọdun 2021.

Ajọ Caf ṣalaye pe ayipada naa waye nitori pe Cameroon beere fun un.

Ṣugbọn ṣa, o ṣeeṣe ki idije AFCON 2021 ni ipa lara idije Champions League nitori awọn agbabọọlu ilẹ Africa bi i Sadio Mane, Mohammed Salah, ati awọn miran to le fẹ gba bọọlu fun orilẹ-ede wọn.