Chelsea vs Tottenham: Lampard àtàwọn agbábọ́ọ̀lù Chelsea dọ́wọ́jọ wó òrùlé Stamford Bridge lu Mourinho àti Tottenham

Frank Lampard ati Jose Mourinho

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbaọjẹ agbabọọlu Chelsea tẹlẹ, to ti di akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu naa bayii, Frank Lampard lo moke ninu ija oun ati ọga rẹ, Jose Mourinho ni papa iṣere Stamford Bridge lọsan ọjọ Satide.

Atamọtaṣe, Olivier Giroud lo gbayo alakọọkọ wọle fun Chelsea nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di iṣẹju mẹẹdogun.

Lẹyin iṣẹju mẹta ti wọn bẹrẹ abala keji ere bọọlu ọhun ni adilemu, Marcos Alonso gba ayo keji sawọn Tottenham Chelsea.

Nisẹ ni akọnimọọgba Tottenha, Jose Mourinho dori kodo lẹyin ti ọwọ iya ba ikọ agbabọọlu rẹ Tottenham Hotspurs.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Mourinho ti ṣe akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea fun igba meji ọtọọtọ.

Amọ Eric Lamela to wọle da ayo kan pada eyi to jẹ ki ere bọọlu pari si ayọ meji si ẹyọkan.