Manchester United vs Manchester City: Ó ti di ìgbà mẹ́ta ní sáà yìí tí Man U dígbájú ru Man City.

O ti di igba mẹta ọtọtọ ni saa yii ti Man U ti n digbaju ru Man City.

Oríṣun àwòrán, Twitter/manchester united

Àkọlé àwòrán,

O ti di igba mẹta ọtọtọ ni saa yii ti Man U ti n digbaju ru Man City.

Manchester City bẹrẹ idije naa daada, ṣugbọn wọn ko fi bẹ ẹ halẹ lawọn asiko ti bọọlu ba wa ni ikawọ wọn, ṣugbọn Manchester United ni tiẹ gboro pupọ.

Agbabọọlu Man U, Anthony Martial lo kọkọ fi goolu sina iya fun Man City nigba ti idije naa wọ iṣẹju mọkandinlọgbọn.

Man U tete gba ara wọn silẹ ninu ina ogun ti Man City kọkọ da ni ibẹẹrẹ idije naa, lati igba naa ni wọn si ti n ṣe daada nigba ti idije naa wa laarin iṣẹju mẹẹdogun si ogun isẹju abala akọkọ.

Man U fi bọọlu kilọ fun Man City ni ẹẹmelo kan, ki wọn o to fi titete ronu gba bọọlu kan si awọn Man City.

Lati igba ti Martial si ti gba bọọlu sinu awọn ni nkan ti n gbona janjan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Botilẹjẹ pe Manchester City ja fita-fita, Manchester United papa tun gba bọọlu miran wọle lati ọwọ Scott McTominay, nigba ti idije naa wọ iṣẹju mẹrindinlọgọrun.

Ni aṣọ iyi ba bọ patapata lara Man City, nitori igba kẹta niyii ti Man U na wọn ni saa yii.

Ìpadàbọ̀wá Ancelotti!Chelsea fi 4-0 kan Everton mọ́lẹ̀ bí àgbò lábẹ́ òrùlé Stamford Bridge

Oríṣun àwòrán, Getty Images/premier league

Àkọlé àwòrán,

Ode iya ni Everton lọ pẹlu bi Chelsea ṣe fi iya ajẹbolori ṣe wọn lalejo ni Stamford Bridge.

Idije naa rọrun pupọ ju fun ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea. Everton ti faaye gba wọn ju.

Abala akọkọ idije naa ko ti i de ibi kan to ti da bi i pe ode ko ni dara fun Carlo Ancelotti. Niṣe ni Chelsea fi ọ̀bẹ̀ goolu ge Everton wẹlẹwẹlẹ.

Adilemu fun ẹgbẹ agbabọọlu, Jordan Pickford gọ ara rẹ, ko yara rara bi Mason Mount ọmọ ẹgbẹ agbọọlu Chelsea ṣe ya bara, to si gba bọọlu sinu awọn . Lo ba di ookan soodo nigba ti idije wọ iṣẹju mẹrinla.

Àkọlé fídíò,

International Womens day: Àwọn obìrintọ́kasí pàtàkì ìbáraẹnidọ́gba láárin ọmọnìyàn

Ha, adilemu Everton, Jordan Pickford ko tun ri nkankan 'piiki' o.

Ṣe ni Pedro rọrọ pẹ 'omi Jordan' silẹ, to si gba bọọlu sinu awọn. Lo ba di meji soodo ni abala akọkọ idije naa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Igba akọkọ ti Pedro yoo gba bọọlu sinu awọn niyẹn ni saa Premier League yii.

Nkan i ba tun ṣẹnu're fun Chelsea nigba ti idije naa wọ iṣẹju mejidinlọgbọn.

Kini Kurt Zouma n ro naa? O fi bọọlu silẹ fun Richarlison, to gba siwaju, to si paasi rẹ si Dominic Calvert-Lewin, ṣugbọn niṣe ni oun yi bọọlu roborobo lati ọna jijin.

Lo ba ja sofo!

Ode iya ni Everton lọ pẹlu bi Chelsea ṣe fi iya ajẹbolori ṣe wọn lalejo ni Stamford Bridge. Ko pẹ ti abala keji idije naa bẹrẹ ni William tun fi kun omije oju ẹgbẹ agbabọọlu Everton nigba to gba bọọlu sinu awọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Carlo Ancelotti ti fi igba kan jẹ olukọni Chelsea, ko da o gba ife ẹyẹ liigi naa pẹlu wọn

Lọrọ Everton ba di ajẹkun iya ni o jẹ..., bi orin ẹnikan oke ọhun.

Ko pe iṣẹju maarun ti William pa wọn lẹkun, ni Giroud tun bu iyọ si oju egbo adaa'jina wọn, ni Chelsea ba ni ami ayo mẹẹrin, ti odo si dagbada iya bọ Everton l'ọrun.

Fẹran jẹkọ gbaa ni idije naa jẹ fun Chelsea.