Sleeping naked: Ìdí mẹ́ẹ́rin tí sísùn ní ìhòhò lé gbà ṣe ara a rẹ l'óore

Obinrin to sun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọpọlọpọ eniyan lo maa n wọ kaba, ṣokoto atẹwu, ẹwu nla, awọtẹlẹ ati oriṣiriṣi aṣọ miran lati sun ni alẹ nitori pe o tẹ wọn lọrun lati ṣe bẹ.

Ṣugbọn njẹ o mọ pe sisun lai wọ nkankan ni anfaani to le ṣe fun ọ?

Oorun sisun jẹ ọkan lara awọn nkan to ṣe pataki ti gbogbo eniyan maa n ṣe ni alẹ, oorun sisun si ni anfaani lọpọlọpọ to n ṣe fun ilera.

Botilẹjẹ pe awọn onimọ nipa eto ilera sọ pe ko ti i si iwadii kankan to sọ pe sisun ni ihoho lalẹ dara ju sisun pẹlu aṣọ lọ.

Ṣugbọn, awọn atọnisọna ere idaraya maa n gba awọn eniyan nimọran lati ma a bọ aṣọ ki wọn o to sun.

Kris Ero to jẹ onimọ nipa ilera pipe sọ fun BBC Pidgin ninu ifọrọwerọ kan, awọn idi to fi dara ki awọn eniyan o maa sun lai wọ aṣọ.

O maa n din ooru ku lati sun daada

Ti ooru ba mu, o dara ki o jẹ ki atẹgun o fẹ si ọ lara.

O sọ pe itura ti atẹgun ba fun ara a rẹ yoo sọ fun ara rẹ pe asiko ti to lati sinmi.

Àkọlé fídíò,

Fadeyi Oloro: Ọfọ̀, àyájọ́ kò ràn án lọ́jọ́ tí 'ṣó o láyà' bá a lálejò

Nitori na, sisun ni ihoho yoo fun agọ ara rẹ ni anfaani lati ma gbona, eyi yoo si ran ọ lọwọ lati sun daada.

Bẹ ẹ naa ni yoo sọ bi o ṣe gbadun oorun rẹ si.

Ara to jọlọ

Nitori pe sisun ni ihoho le fun ọ ni oorun to gbamuṣe, o tun le mu ki awọ ara rẹ ko jọlọ.

Iwadii sọ pe ti o ba sun daada, yoo ra awọ ara rẹ lọwọ lati jọlọ, ati ni ilera pipe. Bi sisun ni ihoho ba wa le ran ọ lọwọ lati ni eyi, o o ri pe iyẹn tun dara.

O maa n din aarẹ ara ati ifoya ku

"Ti a ba n gba awọn ti ko ri oorun sun ni imọran nitori wahala ti wọn n ṣe, a maa n bi wọn pe aṣọ melo ni wọn maa n wọ sun, Kris sọ bẹ.

A si maa n gba wọn ni imọran pe ki wọn o ma wọ aṣọ sun, nitori pe yoo mu ki ara wọn o balẹ dara-dara ti wọn ba fẹ ẹ sun.

Ibaṣepọ to dara pẹlu ololufẹ rẹ

Kris Ero sọ pe, ti ara iwọ ati ololufẹ rẹ ba n kan ara wọn nigba ti ẹ ba sun si ẹgbẹ ara yin, yoo ran yin lọwọ lati maa wu ara yin.

Nitori naa, "sisun ni ihoho ma n mu ki ibalopọ o waye laarin tọkọ-taya