LASK vs Manchester United: Ighalo fi góòlù àrámọ̀ndà góòlù àrámọ̀ndà ló fi gbẹyẹ lọ́wọ́ LASK fún Manchester United

Odion Ighalo ati Juan Mata Image copyright Getty Images

Bi ọmọ ẹni dara, ẹ jẹki a wi. Ẹlẹgan an nikan ni yoo sọ pe ẹlẹsẹ ayo Odion Ighalo n fakọyọ lọwọlọwọ fun ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, Manchester United.

Lẹyin awọn goolu to kọkọ gba sawọn ni kete to darapọ ẹgbẹ agbabọọlu Man U, Ighalo lo gba goolu akọkọ wọle fun Man U ninu abala kinni ''round of 16'' idije Europa ti wọn gba pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu LASK.

Aramọnda goolu ni goolu ọhun ti Ighalo fi ṣẹ awọn alatako leegun ẹyin lalẹ Ọjọbọ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ayo marun un sodo ni Man fi ṣagba LASK, Daniel James lo gba goolu keji sawọn nigba ti Juan Mata lo gbayo ẹlẹẹkẹta wọle ki Mason Greenwood ati Pereira to fi ọba lee

Image copyright Getty Images

Ẹwẹ, ajọ UEFA ko gba ki awọn ololufẹ awọn ẹgbẹ agbabọọlu meejeji wọlẹ lati wo wọn nitori aarun coronavirus to n tan kalẹ kaakiri agbaye.

UEFA wọ́gilé ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Real Madrid àti Manchester City nítorí coronavirus

Bi awada bi ere aarun coronavirus ti di ajakalẹ aarun kaakiri agbaye bayii, eyi to si ti mu ki awọn eeyan maa so ọpọ apejọpọ ati idije ere idaraya rọ.

Ẹru atu itankalẹ aarun yii kan naa lo ti mu ki ajọ UEFA so abala keji ifẹsẹwọnsẹ idije Champions League laarin Real Madrid ati Manchester City rọ bayii.

Ọjọ Iṣẹgun ọsẹ to n bọ lo yẹ ki Man City gbalejo ifẹsẹwọnsẹ ọhun tẹlẹ ki ajọ UEFA to wọgilee.

UEFA wọgile le ere bọọlu lẹyin iyatọ gbogbo awọn agbabọọlu Real Madrid fun ayẹwo ki wọn le mọ bo ya wọn ti lugbadi aarun coronavirus.

Ẹgbẹ agbabọọlu Man City lo jawe olubori ninu abala akọkọ ere bọọlu ọhun ni papa iṣere Santiago Bernabeu.

Ami ayo meji si ẹyọkan ni Manchester City fi ṣagba Real Madrid ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.

Abala keji ifẹsẹwọnsẹ laarin Juventus ati Lyon naa to yẹ ko waye lọjọ kan naa ko ni waye mọ.

Ìbòòsí o! Ìṣọwọ́ gbá bọ́ọ́lù Atletico kò tọ̀nà àmọ́ a gba ìjákulẹ̀ wa - Liverpool

Alakoso fun ikọ agbabọọlu Liverpool, Jurgen Klopp ti n kawọ leri lori ilu bara ti alatako wọn, Atletico Madrid na wọn, to si ni nkan ko jọ ara wọn nipa ilana isọwọ gba bọọlu naa.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ naa to waye lọjọru, ni Atletico ti fakọyọ pẹlu ami ayo mẹta si meji, ti ireti ikọ Liverpool lati raga bo ipo asaaju rẹ ninu idije awọn akọni agbaabọọlu nilẹ Yuroopu, si fori sanpọn.

Image copyright Getty Images

Ikọ Liverpool lo ti wọ asekagba idije naa lawọn saa meji ere bọọlu to kọja, ti Klopp si n figbe ta bayii pe isọwọ gba bọọlu Diego Simeon ti ikọ Atletico ko tọna.

"Inu mi ko dun rara si isesi wa, o nira lati kopa ninu iru ifẹsẹwọnfẹ yii, mo tiẹ n wa iru ọrọ ti maa fi se apejuwe rẹ. Wọn ko gba bọọlu bo se yẹ amọ wọn koju wa bo se yẹ."

Image copyright Getty Images

"A ti gba kadara wa ati abajade ifẹsẹwọnsẹ ọhun amọ ko dun mọ wa ninu. Mo mọ pe n ko mọ baa se n gba ijakulẹ mọra, paapa nigba ti awọn ọmọ ikọ agbabọọlu mi saayan to pegede lati koju agba ọjẹ agbabọọlu meji lagbaye".

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionWaste to Wealth: Ẹ̀gbin tìrẹ ni èròjà táwọn èèyàn míràn fi n ṣiṣẹ́ ajé, okoòwò ńlá ni

Ijakulẹ yii ni igba kẹrin ti ikọ agbabọọlu Livepool yoo fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ọtọọtọ amọ wọn si ni pọnti mẹẹdọgbọn lati wa loke idije liigi premier.

Image copyright Getty Images

Related Topics