Coronavirus: Agbábọ́ọ̀lù Manchester United, Paul Pogba ṣètò owó dídá fún coronavirus, ó tún jẹ́jẹ́ àtìlẹ́yìn

Paul Pogba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Igba akọkọ kọ niyii ti Pogba fi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ sọ ori iranlọwọ ṣiṣe.

Agbabọọlu aarin fun Manchester United, Paul Pogba ti gbe eto owo dida kalẹ, to si tun jẹjẹ lati ṣeranwọ owo fun ajọ to n mojuto eto ilera awọn ọmọ de l'agbaye, Unicef, lati fi ran awọn smọde to ni aarun coronavirus.

Ọmọ orilẹ-ede France ọhun sọ pe oun yoo sọ owo naa di ilọpo meji, to ba ti pe ẹgbẹrun mẹtadinlọgbọn Pọhun, to jẹ afojusun oun.

O sọ pe " ipa ti iru ajakalẹ aarun bayii yoo ni lara awọn ọmọde to jẹ talaka ati alaini oluranlọwọ le l'agbara pupọ".

"Ayẹyẹ ọjọ ibi mi niyii, mo si dupẹ pe emi, ẹbi mi, ati awọn ọrẹ mi wa ni ilera pipe. Ṣugbọn ṣa, kii ṣe gbogbo eniyan lo wa ni ilera pipe lasiko yii.

"A nilo lati sowopọ, fimọṣọkan niru asiko bayii."

Wọn yoo lo owo naa lati fi ra awọn eroja itsju alaisan bi i ibọwọ, iboju fun iṣẹ abẹ, ati gilaasi oju fun awọn oṣiṣẹ eto ilera.

Igba akọkọ kọ niyii ti Pogba fi ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ sọ ori iranlọwọ ṣiṣe.

Lọdun to kọja to pe ọdun mẹrindinlọgbọn, Pogba ṣe ikowojọ owo to le ni ẹgbẹrun meje Pọhun, fun ajọ kan to n pese omi to mọ fun awọn to nilo o rẹ.