Coronavirus: Agbábọ́ọ̀lù Man U tẹ́lẹ̀, Marouane Fellaini, Paulo Dybala àti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lùgbàdì covid-19

Marouane Fellaini Image copyright Getty Images

Agbabọọlu ikọ Manchester United tẹlẹ, Marouane Fellaini ti ko arun coronavirus.

Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ, lorilẹede China, Shandong Luneng lo kede ọrọ naa laarọ ọjọ Aiku.

Fellaini to darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Shandong Luneng ninu oṣu kinni lati Manchester United pada si China lọjọ Ẹti to kọja lọ ko to di pe ayẹwo fihan pe o ti lugbadi arun covid-19.

Ẹgbẹ agbabọọlu rẹ sọ pe Fellaini ko ṣe ojojo tabi iba, bẹẹ ni ko si apẹẹrẹ arun coronavirus kankan lara rẹ nigba to pada de.

Ṣugbọn o ti wa ni iyasọtọ bayii fun itọju, Fellaini ni agbabọọlu akọkọ ni idije liigi ilẹ China to gbajugbaja julọ ti yoo kọkọ ko arun naa.

Ajakalẹ arun coronavirus lo jẹ ki wọn sun ibẹrẹ idije liigi bọọlu orilẹede China siwaju lai lọjọ.

Image copyright Getty Images

Ọjọ kejilelogun oṣu keji ọdun yii ni idije naa ko ba bẹrẹ tẹlẹ ki ajakalẹ arun covid-19 to bẹrẹ.

Ẹwẹ, gbajugbaja agbabọọlu AC Milan tẹlẹ, Paolo Maldini ati ọmọ rẹ Daniel naa ti ko coronavirus.

Bakan naa, ẹlẹsẹ ayo ẹgbẹ agbabọọlu Juventus, Paulo Dybala naa ti lugbadi arun ọhun.

Dybala kede loju opo Instagram rẹ pe oun ati ọrẹbunrin oun, Sabatini ti ko arun ko arun covid-19.

Amọ, o ni ko ṣi ewu fawọn mejeeji nitori ara awọn ti n ya bọ diẹdiẹ.

Dybala ni agbabọọlu Juventus kẹta ti yoo larun naa lẹyin Daniele Rugani ati Blaise Matuidi ti kọkọ lufgbadi arun ọhun.