Ronaldinho: Agbábọ́ọ̀lù Brazil tẹ́lẹ̀, Ronaldinho gba ìtúsílẹ̀ kúrò lẹ́wọ̀n, àmọ́...

Ronaldinho pẹlu awọn ọrẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, EPA

Agbabọọlu Brazil tẹlẹ, Ronaldinho ti gba itusilẹ lọgba ẹwọn lorilẹede Paraguay.

Amọ, ijọba ilẹ Paraguay si fi ofin de e wi pe ko gbọdọ jade nile.

Lọjọ kẹfa oṣu kẹta to lọ ni wọn mu Ronaldinho ati arakunrin rẹ, Roberto Assis lori ẹsun pe wọn lo ayederu iwe irina wọn orilẹede Paraguay.

Awọn mejeeji gbọdọ wa ni igbele bayii titi di igba ti igbẹjọ wọn yoo fi bẹrẹ.

Ṣugbọn Ronaldinho ati arakunrin rẹ sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.

Agbẹjọro wọn tiẹ ṣapejuwe igbesẹ ijọba naa lati fi wọn si ahamọ iwa ta ni yoo mu mi eleyi to lodi si ofin.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Adajọ Gustavo Amarilla ara gbedeke to wa ninu beeli awọn mejeeji ni pe wọn ko gbọdọ sa lọ.

Ronaldinho rinrin ajo lọ si orilẹede Paraguay tẹlẹ lati ṣe ifilọlẹ iwe rẹ ati ipolongo fawọn ọmọ ti obi wọn ko ri ọwọ họri.

Ronaldinho to gba ife ẹyẹ agbaye pẹlu Brazil lọdun 2002 gba bọọlu fun Paris St-Germain, Barcelona ati AC Milan ilẹ Yuropu ko to fẹhinti lẹyin to ṣoju Fluminense fun igba diẹ ni Brazil.