Manchester United: Paul Pogba sọ pé òun ti ṣe tán láti padà sórí pápá

Pogba

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Agbabọọlu fun Manchester United, Paul Pogba sọ pe ebi àṣeyọrí lo n pa oun ju bayii lẹyin ti oun padanu ọpọlọpọ ọjọ ninu idije saa yii nitori ifarapa.Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2019, ni Pogba ti gba bọọlu kẹhin, lẹyin to ni ọgbẹ́ ni ẹsẹ̀ ni ibẹrẹ ṣaa.Pogba sọ pe "airikan ṣe kan ti su oun tipẹ", ati pe oun yoo pada sori pápá igbaradi nikete ti aarun coronavirus ba tan nilẹ.

Àkọlé fídíò,

Ogundiya: Àṣìṣe Dókítà ló sọ mi di aláàbọ̀ ara lórí kẹ̀kẹ́

Oṣu Kinni ọdun ni wọn ṣe iṣẹ abẹ fún gbajugbaja agbabọọlu naa.Pọgba sọ fun ikọ̀ agbohunsafẹfẹ Manchester United pe oun ko ti i la iru nkan bẹẹ kọja ri lati igba ti oun ti n gba bọọlu jẹun, sugbọn oun gba kadara.O ni: "Mi o ro pe awọn eniyan mọ nkan to ṣẹlẹ si mi gan-an."

Pogba ṣalaye pe: "Mo fi ẹsẹ mi ṣẹṣẹ lasiko ti a n gba bọọlu pẹlu Southampton ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ.

Eyi jẹ ibẹrẹ ṣaa, mo si mu u mọra fun igba pipẹ; mo n lọ fun igbaradi, mo si tun n gbiyanju lati fi gba bọọlu.

Lẹyin ti mo dawọ gbogbo eyi duro ni mo sakiyesi pe egungun mi ti yẹ̀.

Ogbontarigi agbabọọlu naa tẹsiwaju pe: "Wọn ba mi fi nkan we e nileewosan. Sugbọn lẹyin asiko diẹ, egungun naa tobi si i, ni mo ba tun pada ṣenu isẹ.

Ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Watford ati Newcastle ni mo gba kẹyin ninu oṣu Kejila, ti mo tun fi n ni inira." Ṣugbọn lẹyin isẹ abẹ ti wọn ṣe fun mi, ara mi ti ya. Mo si ti ṣetan lati pada ṣenu isẹ."Ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin ni wọn kọkọ sun idije Premier league siwaju, lẹyin naa ni wọn tun sun un ni ọgbọnjọ, oṣu Kẹrin, nitori ajakalẹ arun coronavirus to n gba ẹbọ lọwọ gbogbo agbaye yiii.

Àkọlé fídíò,

Yoruba Culture: ọjọ́ méje ni wọ́n fí n rẹ ẹ̀kú Danafojura kó tó jáde