Mike Tyson vs Roy Jones: Ìjà Mike Tyson pẹ̀lú Roy Jones Jr kò ní wáyé mọ́ lóṣù tó ń bọ̀- The Ring

Roy Jones ati Mike Tyson

Oríṣun àwòrán, Instagram/miketyson

Ija laarin abẹṣẹ ku bi ojo to ti fẹyin ti, Mike Tyson ati Roy Jones ti di siso rọ bayii.

Ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan an, ọdun 2020 yii lo yẹ ki ija naa waye tẹlẹ, ṣugbọn ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kọkanla ni ija ọhun yoo waye bayii.

Ileeṣẹ The Ring sọ ninu iroyin kan to gbe jade pe awọn onigbọwọ sun ija naa siwaju lati le fi ija naa pa owo daadaa.

Igba akọkọ ree ti gbajugbaja abẹṣẹ ku bi ojo, Tyson yoo maa lewọ ninu ẹṣẹ kikan lẹyin to ti fẹyinti ni bii ọdun mẹẹdogun sẹyin.

Ni Carson ni California ni ija naa yoo ti ṣẹlẹ.

Adari ajọ to n ri si ere idaraya nipinlẹ California, Andy Foster ti sọ tẹlẹ pe ija laarin Tyson ẹni ọdun mẹtalalaadọta ati Jones, ẹni ọdun mọkanlelaadọta da bii eremọde tabi igbaradi fun ija.

Ṣugbọn Jones sọ pe oun ṣetan lati na tan bi powo pelu Tyson nitori oun ko wo ija gẹgẹ bi eremọde rara.

Ọdun 2005 ni Tyson ja kẹyin nigba ti Kevin McBride lu u lalubami.

Oríṣun àwòrán, Instagram/miketyson

Ọdun 2018 ni alatako rẹ, Jones kẹyin, oun lo si bori alatako rẹ, Scott Sigmon lọdun naa.

Àkọlé fídíò,

BBC Africa Eye: ìwádìí ìkọ̀ks BBC fihàn pé àwọn kan ń jí ohun èèlò ìdáàbòbò ìjọba tà nígbo