Giroud 100th cap: fi àràmọ̀ndà góòlù méjì ṣayẹyẹ ìfẹsẹ́wọnsẹ̀ ọgọ́rùn ún tó gbá fún France

Olivier Giroud

Oríṣun àwòrán, Instagram/giroud918

Ọpọ olololufẹ ere boolu lo bu ẹnu ẹtẹ lu ẹlẹsẹ ayo, Olivier Giroud lẹyin to kuna lati gba goolu kankan sawọn fun ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Faranse ninu idije ife ẹyẹ agbaye lọdun 2018.

Ṣugbọn Giroud ya agbado ha si awọn to maa n tako o lẹnu lalẹ Ọjọru nigba to gba goolu aramọnda meji ọtọtọ sawọn ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọọrẹ to waye laarin ilẹ Faranse ati Ukraine.

Ọjọ manigbagbe ni alẹ Ọjọru ọjọ keje oṣu kẹwaa, ọdun 2020 jẹ fun Giroud nitori ifẹsẹwọnsẹ to fakọyọ ninu rẹ yii lọ jẹ ifẹsẹwọnsẹ ọgọrun un ti yoo kopa ninu rẹ fun ilu baba rẹ, Faranse.

Alabami ni ilẹ Faranse lu Ukraine ninu ere bọọlu naa lẹyin ti wọn gba goolu meje ọtọtọ wọle ti Ukraine si rapala da ẹyọkan ṣoṣo pada.

Amọ ara ọtọ ni goolu meji ti Giroud ẹni ọdun mẹtalelọgbọn gba wọle ninu rẹ jẹ.

Giroud ko si lara awọn ẹlẹsẹ ayo meji akọkọ lẹgbẹ agbabọọlu Chelsea to ti gbabọọlu jẹun, bakan naa ọpọ ni ko nigbagbọ ninu rẹ nigba to fi wa pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal.

Ṣugbọn ọrọ Giroud ti di okuta tawọn ọmọle kọ silẹ to ti wa di pataki igun ile bayii pẹlu ara to fi bọọlu da nigba ti orilẹede Faranse waako pẹlu Ukraine.

Lapapọ, Giroud ti gba goolu mejilelogoji sawọn bayii fun orilẹede Faranse ninu ọgọrun un bọọlu to ti ṣoju ilẹ naa.

Oun ni ẹleṣẹ ayo keji to gbabọọlu sawọn julọ fun orilẹede Faranse, agbaọjẹ agbabọọlu Arsenal tẹlẹ ri, Thierry Henry lo wa ni ipo kinni.

Goolu mẹsan an ni Henry fi ju Giroud lọ eyi ti o si lanfaani lati ba a ati lati ju u lọ.