Benin vs Nigeria: Mínísítà ní kí Super Eagles lọ lu Benin mọ́lé nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àti pegedé fún AFCON 2021

Ahmed Musa pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Twitter/Super Eagles

Minisita ere idaraya ati ọrọ idagbasoke awọn ọdọ, Sunday Dare ti rọ ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles Naijiria pe ki wọn lọ lu alatako wọn wọn, Benin Republic mọle.

Super Eagles gunlẹ si Benin Republic lọjọ Ẹti fun ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije ere bọọlu ilẹ Afirika, AFCON 2021.

Ninu ọrọ iyanju rẹ sawọn agbabọọlu Naijiria, minisita só fun wọn pe ''aileja lojude ile baba mi o de bi, ẹ bẹrẹ daadaa, ṣugbọn ni bayii, ẹ gbọdọ pari daadaa bakan naa.

Ko si ere bọọlu to rọrun, nitori naa, ẹ maa foju di awọn agbabọọlu Benin Republic tori pe ko si ọbọ kan ni dere mọ lagbo ere bọọlu afẹsẹgba,'' minisita lo sọ bẹẹ.

Ọgbẹni Dare sọ fawọn agbabọọlu Naijiria pe ki wọn sa gbogbo ipa wọn lati fo bi ẹyẹ idi ti orukọ inagijẹ wọn n jẹ.

Naijiria lo si wa loke tente lori isọri kejila awọn orilẹede to n gba ifẹsẹwọnsẹ ati pegede fun idije AFCON 2021.

Ẹgbẹ agbabọọlu Super Eagles ti jawe olubori ni meji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹrin ti wọn ti gba nigba ti wọn ta ọmi meji bakan naa.

Orilẹede Benin lo wa ni ipo keji lẹyin tawọn naa jawe olubori ninu ere bọọlu meji ṣugbọn wọn fidi rẹmi ninu ọkan nigba ti wọn ta ọmi ninu omiran.

Ẹwẹ, ajọ to n ri si ere bọọlu afẹsẹgba ni Naijiria, NFF ti sọ pe awọn ọmọ Naijiria yoo ri ifẹsẹwọnsẹ naa wo loju opo Twitter rẹ.