Nigeria vs Benin: Paul Onuacha ló fi góòlù ra iyì fún Super Eagles

Awọn agbabọọlu Super Eagles

Oríṣun àwòrán, Other

Ẹgbẹ agbabọọlu agba Naijiria, Super Eagles ti na Squirrels ti Benin Republic.

Bi wọn ṣe bori ninu idije naa to waye ni papa iṣere Stade Charles de Gaulle ni Poto Novo, Benin, ti mu ki wọn o koju oṣuwọn lati kopa ni nations cup.

Ami ayo kan si odo ni Super Eagles fi fẹyin Squirrels janlẹ.

Asiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju mẹtalelaadọrun ni Paul Onuacha gba bọọlu sinu awọn, lẹyin ti ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ti ta ọmi odo.

Ṣaaju asiko yii, ami kan pere ni Naijiria nilo lati koju osuwọn fun Nations Cup, ti yoo waye ni ọdun to n bọ ni Cameroon.