Òdùduwà Nation: YWG ní òun kò fẹ́ ìdásílẹ̀ orílẹ̀èdè Yorùbá torí ó lọ́wọ́ òṣèlú nínú

Igboho ati ami idam YWG

Olùdásílẹ̀ Yorùbá Welfare Group YWG, Comrade Abdulhakeem Adegoke ti ba BBC Yoruba sọrọ lori idi ti ẹgbẹ rẹ̀ fi n tako iyapa Naijiria.

Ẹgbẹ́ YWG ló kọ̀ láti kín olóyè Sunday Adeyemo, tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Sunday Igboho lẹ́yìn, lórí ìpínyà ẹ̀yà Yorùbá kúrò lára orilẹ̀ède Nàíjíríà àti ìdásílẹ̀ ‘Oòduà Nation‘.

Adegoke ni ipolongo idasilẹ orilẹede Oodua ó ti ni ọwọ́ òṣèlú nínú.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe ẹ̀yà Yorùbá kìí fí orí bíbẹ́ ṣe òògùn orí fífọ́, nítorí náà ó tí hàn gbangba gbàngbà pé ọ̀pọ̀ àwọn tó wà lẹ́yìn ọ̀rọ̀ Yorùbá Nation ni àwọn tí kò rí jẹ́ mọ́ lábẹ́ ìjọba APC tó wà lóde yìí.

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Ó ní nínú ìwádìí tí ẹgbẹ́ náà ṣe fihan pe ọ̀kẹ́ àìmọye ọmọ Yorùbá àti Hausa ló ti dàpọ̀ nípa ìgbéyàwó, tí òbítíbitì owó sì tún wà gẹ́gẹ́ bi dúkíà ajọni wọn.

Adegoke ni àṣìṣọ ọ̀rọ̀ ńla ni ọ̀rọ̀ tí Sunday Igboho sọ nítorí pé ìdá ààdọ́rùn lé nínú àwọn tó ń gbàrùkù tí ọ̀rọ̀ Oòdua Republic, ló jẹ́ àwọn ti ìjọba bọ́ lọ́wọ́ wọ́n lánàá.

"Wọ́n jẹ, wọ́n mu, wọ́n ná, wọ́n tún lò nínú ìjọba àná, tí gbogbo rẹ̀ tí wá bọ́ lọ́wọ́ wọn báyìí.

" Ìjà ẹgbẹ́ òṣèlú ni wọ́n ń jà kìí ṣe ìfẹ́ ará ìlú"

Oríṣun àwòrán, Abdulhakeem Adegoke Face book

" Kí ló dé tí wọ́n kò sọ pé kí Hausa, Igbo àti gbogbo elédè mííràn máa kúrò nílẹ̀ Yorùbá, kí gbogbo ọmọ Yorùbá ni gbogbo àwọn ìpińlẹ̀ míràn tó kù náà má a bọ̀ wá sílé.

Sùgbọ́n wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n kan ni kí Hausa níkan má lọ, ṣe Yorùbá àti Igbo tan ni? Sé ọmọ Oòdua ni Igbo ní, tó fí jẹ́ pé Hausa nìkan ni wọ́n ni kí ó má lọ?

Ìdásílẹ̀ Òòdúá Nation kìí ṣe ǹkan tí ẹnikan yóò jí láàrọ́ ọjọ́ kan tí yóò bẹ̀rẹ̀, ó ni àwọn eeyan tó yẹ kí wọ́n jòkó jíròrò lórí ọ̀nà tí wọ́n yóò gbe gbà."

Àkọlé fídíò,

Kò sí ìgbà kankan tí Yorùbá jókòó pé ki Igboho lọ kéde ìyapa kúrò ní Nàíjíríà

Adegoke ni àwọn ọwọ́ òṣèlú ni ọ̀rọ̀ yìí ní nínú, kò sì ṣe e ṣe kí gbogbo Yorùbá wà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan náà, olúkúlùku ni yóò pín káàkiri.

"Ìbéèrè tí mò ń bèèrè ni pé, ṣe ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nìkan ló n fẹ́ Òòdùà Nation ni?

Tó bá jẹ́ pé wọ́n kó gbogbo Yorùbá pọ̀, tí kí ṣe pé àwọn tó ti jẹ́, tí wọ́n ti mu nínú ẹgbẹ́ òṣèlú tó kọja láye Jonathan, lábẹ́ Obasanjo àti Atiku, ló wá jáde pé wọ̀n fẹ́ lọ sí Yorùbá Nation".

Àkọlé fídíò,

Blighted Ovum: Obìnrin kan sọ ohun tójú rẹ̀ rí nígbà tí oyún bàjẹ́ lára rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹta

Olùdásílẹ̀ Yoruba Welfare Group tún fi kun pé, ègún tó n ja ìràn Yorùbá láti àyé Aláafin Aolẹ ni ìlú Oyo àti Afonja, ti èdè wọn kò fi yé ara mọ sì ló n jà títí di àsìkò yìí.

O ní àwọn tí wọ́n ń bèèrè fún Yorùbá Republic, wọ́n kò se láti gbèjà Yorùbá bí kò ṣe pé aájò àra wọ́n ni wọ́n ń ṣe.

Adegoke wa gba ìràn Yorùbá ní ìmọ̀ràn pé, ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà ni pé ki a pada sí ẹsẹ ààrọ́, níbí tí ẹkùn kọ̀ọ̀kan yóò tí má dari ọ̀rọ̀ ajé rẹ̀.