Ní ìmọ̀ nípa bi BBC ṣe n ṣiṣẹ́ ìròyìn ayélujara nínú òtítọ́ àti láì ti igbá kan bọ̀ ọ̀kan nínú

BBC jẹ́ ìlúmọ̀ọ́ka láàrín àwọ́n olólùfẹ́ rẹ̀ lórìlẹ̀-èdè UK àti jákèjádò àgbáyé, à ń ṣe àgbékalẹ̀ ìròyìn tí ẹ le fọkàn tán. Ẹ̀rọ ayélujára wa, Móhùnmáwòràn àti Rẹdíò, ìròyìn tó pé ti ko sì ní ẹja ń bákan nínú, ti ó dádúró tí ó sì wà fún òótọ́ ní BBC ń ṣe.

Èròjà ìlànà tí BBC ń gba ṣe ìròyìn: Ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ BBC ní ìfẹ́ nítori pe ìròyìn wa kò ni ẹja n bákan nínú òòtaọ́ yìí si ló jẹ ki wọ́n dúro tìwá gbágbáágbá. Ilé iṣẹ́ BBC kò ní bàbá ìsàlẹ̀, à kìí parọ, a sí ní òótọ́. A ní ìfarajì láti mú ìròyìn tó gún reége láì gbé ọmọ ọbà fún ọ̀ṣun, bákan náà ni a maa ń yàgò gédégédé fún ǹkan to ba lé ṣi àwọn olólùlùfẹ́ wa lọ́nà

"Ìfarajì wa fún àìfigbákan bọ̀kan nínú jẹ gbùngbùn ọkọ̀ ìgbákẹ̀le àwọn ènìyàn nínú wa. Nínú gbogbo àwọn ìròyìn tí à ń gbé síta a má ń fi ojú sùnùkùn wo ìròyìn tí a ba fẹ́ gbe síta láti rii dáju pe kìí ṣe èrò ara wa ní à ń gbe jáde. A máa n ṣe àgbéyèwò ìròyìn kan, à ó yẹ gbogbo ẹ̀rí to níṣe jáde pẹlu àìní ẹni ti a ń ṣègbè fún lọ́kan"

A mọ pé ó n ira láti dá ìròyìn tó jẹ́ ojúlowó mọ̀ lári ẹ̀rọ ayélujára. Bákan náà ní a mọ pé ọ̀pọ̀ àwọn olólùfẹ́ wà ló fẹ́ ní òye bí BBC ṣe ń gbé ìròyìn wọ́n jáde.

Nítorí ìdí èyí, BBC ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti sàlàyé ìrú àwọn ìmọ̀ ti ẹ ń kà tàbí wò lóri ẹ̀rọ ayélujára, níbo àti ọ̀dọ̀ tààni ìrú ẹni tó ń gbé ìròyìn náà jáde, àti pé báwo ní wọ́n ṣe kọ ìròyìn náà, nípasẹ̀ èyí, ẹyin gan ó le jẹ́rìí sí ọ̀nà ti ẹ fi lè ní ìgbẹkẹ̀lé nínú ìròyìn BBC

À ń ṣe atọ́ka tó ṣàlàyé ìṣẹ́ ìròyìn tó ṣe gbẹ́kẹ̀lé "ẹ̀rọ ìkàwé", èyí túnmọ sí pé à lè ṣe àwári rẹ̀ nípa lílo èròjà tí a fí ń ṣe àwári ǹkan lórí àwọn èròjà àtẹjíṣẹ́ orí ẹ̀rọ ayélujára, èyí yóò ma ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dá ìròyìn òótọ́ọ́ mọ̀ àti orísun rẹ̀ náà.

ÌLÀNÀ TÓ DÁRA JÙLỌ

Ó ti pẹ́ tí BBC tí ní àwọn ìlànà tó ń gba kọ ìròyìn tí yóò sí wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àlàklẹ tí ó yẹ nínú ètò ìròyìn kíkọ. Láti mú kí ó rọ̀rùn fún yín láti rí bí a ṣe ń lo àwọn ìlànà ìlànà ní yàrá ìkóròyìn jọ wa, a ti kọ gbogbo àwọn ǹkan ti yóò wúlò fún yín sí ipele yìí.

Èrongbà wa: Èròngbà wà ní láti gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe ǹkan ti yóò ṣe àǹfàní fún ará ìlú, ṣíṣe ìṣẹ́ fún àwọn alábara wa nípa pípèsè ìròyìn tó yàtọ̀, tó kú ojú òṣùwọ́n, tí ko sì ni ẹjańbakàn ńinú, bákan náà ni à n kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, à n fí ohun tó ń lọ to wọ́n leti bákan náà ni àn dáwọn lára yá. Fún ẹkúnrẹ́rẹ́ BBC Charter.

Olùdásílẹ̀, Àgbékalẹ̀, Ọ̀nà tí à n gbà rí owó àti Ẹbun: Ilé iṣẹ́ BBC dádúro gedegbe kúrò ńinú ǹkan tó le ta ẹrẹ̀ bá àwọn àlàsílẹ̀ ìlàna ìròyìn ti à ń gbé jáde. Ìdánilójú wà fún àwọn oníbàrá wa pé àgbéjade ìròyìn wà kìí ṣe nítori ìfẹ́ inú ẹnikẹni, yálà olóṣèlú, tàbí àwọn olókòòwò, tàbí ọlọ́dan ni kànkan. Ní ìmọ̀ síi nípa bí BBC ṣe ń rí owó ìsúná rẹ̀ yálà ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tàbí láwọ́n orilẹ̀-èdè òkè òkunBBC Charter on the independence of the BBC.

Ọdún ìdásílẹ̀ ilé iṣẹ́ BBC: A dá BBC sílẹ̀ ń ọjọ̀ kejìdílógun oṣù kẹwàá, ọdún 1922. Ka ẹkúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ níbi history of the BBC.

Òfin to de ìlànà àmúlò: Awọn BBC's Editorial Guidelines ṣe àlàálẹ̀ àwọn ìlànà ti à n gbà ṣe ìsẹ́ ìròyìn ati bí àwọn ìroyin wa yẹ kó wà.

Àwọn ìlà fún àyẹ̀wò

Onírúurú ìlànà ìṣe: Ní ìmọ̀ nípa bi ilé iṣe BBC ṣe farajì fún ṣiṣe àmojúto oríṣiriṣi ẹ̀yà BBC Charter.

Ìjábọ àwọn òṣìṣẹ́ nípà ẹyàmẹya: Mọ̀ nípa bí BBC ṣe ń ṣisẹ́ láti túbọ̀ mú ìwúri ba gbogbo ẹ̀yá, ẹsin àti àwọ̀ BBC's Equality Information Report.

Àwọn Àtúnṣe: Ilé iṣẹ́ BBC ń a fi ara ji fun aseyori ise to n lo geere . Àwọn ìlànà sí àtúnṣe ní a le ri ninu àwọn abala ilàna bí a ṣe ń kọ ìròyìn

Ọ̀nà tí à n gbà ṣe ìwádìí ìròyìn wa gbọdọ̀ dá lóri òòtọ́, èyí ti o ṣe gbéléwọ̀n, tí a si kọọ́ sílẹ̀ ní èdè tó dántọ́ ati pe ko gbodo ni ìtúmọ míràn sí ohun ti a sọ. A gbọdọ jẹ́ olóòtọ́ kí a sì yẹra fún ohun ti a kò mọ̀, iroyin kùbá kùgbé. Ifẹ̀sùn kan, ẹ̀rí nípa àfojúrí nìkan àti àwọn ǹkan míràn ti a kò le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọ̀dọ̀ jẹ́ bi àfiwé pẹ̀lú ǹkan ti ẹlòmíràn ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀

Tí a ba ṣe aṣìṣé, a máá n jáde si gbangba láti tọrọ àforíjì, bákan náà ni a ma ní a máá n gba àwọn ènìyàn níyanjú láti kọ àṣà kíkọ́ ẹ̀kọ́ lára elòmíràn.

Bí a ba ti ṣe atúnṣe si ǹkan ti a ti kọ síta tẹ́lẹ̀, a máá ń pe àkíyesí àwọn alábàráà wà sí àkíyàsí pé à ti ṣe àtúnṣe, pèlú àsìkò ti ìrú àtúnṣe bẹ́ẹ̀ wáye. Tí ó ba jẹ́ pé ìrú àṣìṣe bẹ́ẹ̀ kò yìí ìtumọ tàbí ǹkan ti ìròyín náà lòdí si ìlàna imúṣẹse wa bí àpẹrẹ (àṣìkọ orúkó) à ṣe àyípada lái pe àkíyèsí ẹnikẹni síi.

Àyà fi to ba jẹ́ pe ìrú ìròyìn bẹ́ẹ̀ kìí ṣe fún ìgbà pípẹ́ a nígbàgbọ́ pé irú àkọsílẹ̀ yìí ti a gbé jáde lóri ẹ̀rọ ayélujára yóò dí ǹkan ti yóò ma wa titi fún àtúnlò àti pé a kò ní yọọ́ kúrò. Ẹ̀wẹ̀ a lè rí àwọn ìdí tó le mú ọ̀rọ̀ òfin dáni, kí ó mú ewu dáni fún ọlọdani tàbi kí o ma ba ìlànà tí àn gba ṣe iṣẹ́ ìròyìn ni BBC ti a ko si le ṣe àtúnṣe si, à ki a yọ.

Àwọn ìlà fún àyẹ̀wò:

Àyẹ̀wò/ìwádìí tó yè kooro: Àyẹ̀wọ̀ àti ìlànà pípéyé ni a ti sàlàyé nínú Editorial Guidelines on Accuracy.

Àwọn orísun ti a o lè dárúkọ: Àwọn àlàkalẹ̀ ìmúṣe àti ìtọ́sọ́nà lóri lílo àwọn orísún ti kò lórúkọ wà ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nibi yìí Editorial Guidelines.

Awọn ìlà àyẹwò míiràn:

Àwọn àbọ̀ tó ṣe siṣẹ́ lé lórí: A ṣe àgbékalẹ̀ ìlànà tí BBC ńgba láti moju to aríwisi awọn alábàra wọ́n BBC Complaints Framework..

Olùdarí BBC: Èyí ní àwọn ọ́gá àgbà aláṣẹ ẹka ìròyìn BBC News Board.

Awọn Akọròyìn tó mòye

Ìròyìn BBC tí ó ba jẹ pe BBC ló ṣe ìwádìí rẹ̀ máa ń ni orúkọ àkọròyín àti àwọn akọroyin tó tí wọ́n ní ojúṣe kan pàtó.

Sùgbọ́n àwọn ìròyìn ti a sà káàkíri awọn ìwé ìròyìn míràn, tàbí ti a ba mú ìwádiìí jáde ní àwon ẹka BBC mírà, tàbi ti akọròyìn kan ti kọkọ ṣiṣé lé lori sáájú tẹ́lẹ̀ kò lé gbé orúkọ kankan lóri.

ÀWỌN ONÍRÚURÚ IṢẸ́

Ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC máá ń fi ìyàtọ̀ sí àwọn ìròyin tí a le fí àwọn ìdí rẹ múlẹ̀ àtí àwọn èyí ti àwọn ènìyàn kan sọ èrò ọkàn wọ́n lásán. a máa n lo ẹ̀rọ ìkàwé se àkọle rẹ̀ si ipele mẹ́fà:

  • Ìròyìn - Àkọsílẹ̀ ìròyìn tó dá lóri òòtọ́, yálà tí wan kan foju ri tàbi èyi ti akoroyin fìdí rẹ múlẹ̀, tàbi jábọ ti a tún wádìí rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn onímọ nípa ǹkan náà
  • Àtúpalẹ̀ - Àwọn ìròyìn ti a gbéjáde nípa ǹkan tí onímọ sọ, yálà ti akoroyin BBC tàbi ònímọ miran láti ìta tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi òyé ọ̀rọ̀ to takókó lásiko kan
  • Bíbèrè lọ́wọ́ àwọn tó n wò/gbọ́ wa: Èyí ni àwọn ìroyìn to fẹ́ fi olùgbọ́ kopa láti gbọ́ èrò tí wọ́n
  • Alálàyé- Èyí ni ìròyìn tó fi òkodoro ọ̀rọ̀ múlẹ̀ lóri ìdí tàbi ààyé ti irú ǹkan bẹ́ẹ̀ fi wáye
  • Èróngbà - Ilé ìròyìn BBC kìí ṣègbè, figbákan bọ̀kan nínú tàbi gbé èrò inú wa jáde, sùgbọ́n nígbà míràn a máá ń ṣe àgbéjáde èròngbà àwọn onímọ̀ láti ìta, a má n sàfihàn èrò pẹ̀lú ṣíṣe àkójọ àwọn onímọ pàápàá jùlọ èyí to ba jẹ́ òòtọ́ọ́ àti òkodoro.
  • Àtúnyẹ̀wò - Ìròyin tó ba dálé àgbéyẹ̀wò tó ṣe kókó pàápàá jùlọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ kan, ìṣẹ́ onímọ̀ kàn tó ní èròngba tó ṣe kókó

ÀWỌN ÀPẸRẸ ÀTI ÌTỌ́KASÍ

Àgbéjáde iṣẹ́ wa bótiwù kórí máà n kún ojú oṣùwọ̀n, a máá n ṣe ìwádìí láti orísun to múná dóko pẹ̀lú ẹ̀ri to dáju, àyẹwò fínifíní, ati àgbekalẹ ni ede ti o daju, àti òtitọ. A ngbiyanju lati jẹ olòótọ́ kí a sì sàlàyé nípa ohun ti a ko mọ, bákan náà ni a maa n yago fun wọ́niwọ́n pé.

Lásìkò ti ilé iṣẹ́ ìròyìn BBC bá ti gbarale orisun kan fun ìròyìn rẹ̀, à ó kọ orúkọ ẹní náà sii tí ààyè rẹ̀ bá yọ. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà a máa n tọ́kasi àtẹjáde ìjọba, èyí to ba jẹ mọ ìṣìrò tàbi orísun ọ̀rọ̀ kan to n lọ nita, lati fun yin ni anfani lati dẹjọ fun ara yin lori alaye ipilẹ ìròyìn tábi àlàyé lóri ìròyìn ti à n ṣe.

Nígbà kúúgbà ti to ba yẹ, a máa n fi ìlà ti a o fi de ojú opó àwọn ti ni ìròyìn, tàbi tan imọlẹ̀ si ǹkan ti à ń sọ ínú ìròyìn wa.

ÌLÀNÀ TÍ À Ń GBÀ ṢIṢẸ́

Fún iṣẹ́ to níkìmí nínú, bí iṣẹ́ ìwádìí tàbi kíkọ ìròyìn tó níṣe pẹ̀lú dátà, a máa ń ràn yín lọ́wọ́ láti ni òye bi a ṣe ń se iṣẹ́ wa nípà sísàfihàn bi aṣe ṣe àkójọ dátà àti ìtúpalẹ̀ ohunkohun to ba dabi ẹni pe ó ta kókó, àwọn àròsínú tàbi ìlànà míràn ti a gbà ṣiṣẹ́- bí àpẹẹrẹ, àwọn àpẹẹrẹ ìkẹ́kọ̀ọ́, ìwọ̀n àyẹwò, sisasoju, awọn àlà àìtọ́, báwo ni a ṣe gba dátà, ọ̀nà wo lo gbà báramu lágbàyé, pẹ̀lú ìgbà àti àkókò