Got a TV Licence?

You need one to watch live TV on any channel or device, and BBC programmes on iPlayer. It’s the law.

Find out more
I don’t have a TV Licence.

Jíjábọ̀ ohun tí ń lọ lọ́wọ́

Nípasẹ̀ Olubusola Afolayan àti Adedayo Owolabi

Gbogbo àkókò tí a kọ jẹ́ ti UK

 1. Post update

  Eyi ni opin iroyin yajo-yajo lori bi eto idibo se n lọ ni ipinlẹ Ekiti.

  Sugbọn a tubọ tẹsiwaju lati maa bun yin gbọ nipa awọn iroyin eto idibo ni ipinlẹ Ekiti lori oju opo iroyin wa tii se www.bbc.com/yoruba.

  Ẹ seun pupọ, tẹ dara pọ mọ wa.

 2. Àwọn olùdìbò ń fò fáyọ̀ ní àgọ́ ìdìbò Sẹgun Òní

  Awọn oludibo n fo fayọ nigbati wọn ka esi ibo, ti APC si wọle.

  Ẹgbẹ oselu PDP lo ti n kọkọ fo soke tẹlẹ, amọ nigba ti wọn ka ibo naa, ni APC moke, ti awọn eeyan si n jijo ọpẹ.

  Video content

  Video caption: Ekiti Election: Ìdùnnú subú layọ̀ ní àgọ́ ìdìbó APC
 3. Ti wọn ba gbe apoti idibo rẹ, mase pada wale - Fayose

  Fayose ni kawọn asoju PDP mase pada wale, ti won ba ji apoti idibo wọn lọ.

  Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayose ti sọ fun awọn asoju ẹgbẹ oselu PDP to wa ni awọn agọ idibo lati mase pada wale, ti won ba ji apoti idibo wọn lọ.

  Fayose sọ eyi nigba to n pe ọkan lara awọn asoju ẹgbẹ naa to wa ni Emure Ekiti.

  Fayose ni oun ko fe gbọ awijare, ati wi pe ẹnikẹni ti wọn ba ji apoti idibo rẹ gbe gbọdo waa ri, abi ki o mase pada wa si Ado-Ekiti to jẹ olu-ilu ipinlẹ Ekiti.

  O pari ọrọ rẹ pẹlu owe wipe ‘ole o gbọdọ wa si ile rẹ, ki o gbe ẹru rẹ lọ’.‘

  Gomina Ayọdele Fayose
  Image caption: Gomina Ayọdele Fayose
 4. Olusola Ẹlẹka bori ni agọ idibo rẹ

  PDP - 452

  APC - 105

  PPA - 1

  PANDEL - 1

  Ọjọgbọn Olusọla Ẹlẹ́ka
  Image caption: Ọjọgbọn Olusọla Ẹlẹ́ka
 5. PDP jawe olubori nibudo idibo Fayoṣe

  AD 1

  ADP 2

  APC 106

  PANDEL 1

  PDC 1

  PDP 304

  PPA 2

  PDP jawe olubori nibudo idibo Fayoṣe
  Image caption: PDP jawe olubori nibudo idibo Fayoṣe
 6. Èrò àwọn ololufẹ BBC miran lori idibo Ekiti

  Zury-Olanrewaju Hamzat:O ma se o! Osi, ipọnju ati aimokan-mokan ni ona ti o ga ju leleyi o. Pelu gbogbo ilani loye lori ewu ti o wa nibi ki a ma gba owo ki a to dibo. Ekun gbọn mi fun orilede yio.

  Ibigbami mutairu AlabiSe eni ti won kolu ni egungun re tun ti le bayii, baba feran drama pipo ju, opolo oselu

  Olaleke Olawole: Igba Iṣoro la ma n mọ Olorun, Fayose ti ni Problem, kini idi ti o fi je pe afi dandan Eleka, Fayose want cover up! wa a pe lewon Oleeee.

 7. Àwọn ṣọ́jà ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lu janduku l'Ekiti - Fayoṣe

  Video content

  Video caption: Awọn ṣọja n ṣiṣẹ pẹlu janduku ni l'EKiti
 8. Aṣọ funfun táwọn oludije Ekiti wọ, Se ajọmọ wọn ni? Abi o ni nkan to ba de?

  Aṣọ funfun ni àwọ̀n olùdíje méjì gbòógi nínú ètò ìdìbò gómìnà Ekiti, Olusọla Ẹlẹka PDP ati Kayọde Fayẹmi APC wọ loni ọjọ idibo?

  Aṣọ funfun táwọn oludije Ekiti wọ, Se ajọmọ wọn ni? Abi o ni nkan to ba de?
  Image caption: Aṣọ funfun táwọn oludije Ekiti wọ, Se ajọmọ wọn ni? Abi o ni nkan to ba de?
 9. KókóFayẹmi jawe olubori ni ibudo idibo rẹ̀

  Esi idibo to n tẹ wa lọ́wọ́ fi han pe APC ti jawe olubori ni ibudo idibo ti Fayẹmi.

  APC 186

  APA 1

  PDP 2

  Fayẹmi jawe olubori ni ibudo idibo rẹ̀
  Image caption: Fayẹmi jawe olubori ni ibudo idibo rẹ̀
 10. KókóAPC jawe olubori ni ibudo idibo Ọmọba Adeyeye

  Esi idibo ibudo ti Omoba Adeyeye ti dibo Ekiti.

  APA-1

  PDC-1

  PDP-15

  APC-176

  Void-4

 11. Ekiti Election: Ọkunrin kan sá nígbà ti wọn ló gbé ìbọn

  Awọn oludibo n fẹsun kan ọkunrin to wọ asọ búlù yii pe o mu ibọn wa si ibudo idibo ni eyi ti awọn oludibo pe ọlọpaa.

  Nigba ti awọn ọlọpaa n bii leere pe kin lo wa lara rẹ, ko fesi kankan rara. Nise lo fo ọna si odikeji titi, to si wọ inu ọkọ jiibu SUV Lexus dudu kan to wa nilẹ, to si lọ.

  Video content

  Video caption: Awọn èrò tètè kẹfin pé o gbébọn dání
 12. Fidio àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ tó ya wọ Ekiti

  Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ awọn ọmọ ogun ilẹ̀ ti ya wọ Ado Ekiti to jẹ olu ilu ipinlẹ Ekiti bayii.

  Video content

  Video caption: Ekiti Election: Ọkọ to le ni ogun ni wọn fi ko ologun wa
 13. Awọn oludibo n se ‘see and buy’ ni Ekiti

  Ni wọọdu karun-un ati ikẹfa, ladugbo Okehinmi, awọn ololufẹ ẹgbẹ oselu APC ati PDP n tahun si ara wọ̀n.

  Awon oludibo to ba BBC sọrọ ni Okehinmi, ward 6, unit 5 sọ pe idibo naa ni konu-n-kọhọ ninu lagbegbe naa nitori wọn n gba owo lọwọ awọn oludije.

  Video content

  Video caption: Awọn oludibo ni wọn n se ‘see and buy’ ni Ekiti
 14. INEC yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni ka ìdìbò laago meji ọ̀sán

  Awọn ibudo idibo kọọkan ti pari eto idibo, ṣugbọn awọn miran ṣi n dìbò bayii.

  Ajọ INEC ti kede agogo meji lati fopin si idibo Ekiti lonii.

  INEC yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni ka ìdìbò laago meji ọ̀sán
  Image caption: INEC yóò bẹ̀rẹ̀ sí ni ka ìdìbò laago meji ọ̀sán
 15. Fayoṣe ni àwọn agbófinró ti já ìdìbò gbà lọ́wọ́ INEC

  Fayose ti so pe awon agbofinro ti ja eto idibo gbà mo ajo INEC lọwọ ṣugbọn bi o ti wu ko ri Eleka ni yoo wole.

  O ni oun ni idaniloju pe oun lo ni ida ogorin ninu ọgọrun ìbò ipinle Ekiti.

  Fayoṣe ni àwọn agbófinró ti já ìdìbò gbà lọ́wọ́ INEC
  Image caption: Fayoṣe ni àwọn agbófinró ti já ìdìbò gbà lọ́wọ́ INEC
 16. KókóFayoṣe ti dibo ni Afao Ekiti

  Gomina Fayoṣe ti dibo ni Afao Ekiti. Ayo Fayoṣe wọ gbégun-ọrùn-ró si ọrun rẹ.

  Fayoṣe ti dibo ni Afao Ekiti
  Image caption: Fayoṣe ti dibo ni Afao Ekiti
 17. KókóỌlọ́pàá ti mú janduku ni Emure àti Ado Ekiti

  A gbọ pe loju awọn osisẹ alaabo ni awọn janduku naa ti ji apoti ibo naa gbe. Sugbọn ni kete ti awọn ọlọpaa kogbregbe (SARS) debẹ, ni wọn fi panpẹ ofin gbe awọn janduku naa.

  Ni Ado Ekiti, awọn ọlọpaa naa mu oludibo meji.

  Awon ọlọpaa yọ aworan iṣẹlẹ yii ti akọroyin BBC ya.

 18. Segun Oni sọ̀rọ̀ lórí àwọn tó ń gba N4000

  Segun Oni ni Ẹnikẹni to ba fi kaadi rẹ silẹ lati gba owo ko ni lẹnu ọrọ lati koju isejọba ipinlẹ naa.

  Sẹgun Oni sọrọ naa nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin to dibo ni wọọdu rẹ.

  O fikun pe eto idibo naa n lọ deede, sugbon ẹrọ kaadi wọn n wọ́lẹ̀ to fa ki ẹro pọ lori ila.

  Video content

  Video caption: Segun Oni soro lori awọn tan gba 4000 naira.
 19. Èrò àwọn ará ìlú ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ l'Ekiti

  Diẹ lára ọ̀rọ̀ àwọn ololufẹ BBC ni Facebook niyii:

  Adesanya Folashade Asake: Ibo Ekiti wahala ti poju kinlode gannnn

  Funsho Bernice: Ko poju ni temi....ti o ba fe losi ile awon ole onijibiti lati gba nkan, o nilati munra bi eni to n losi oju ogun ni.

  Olaogun Olusola Isaac: Itanje lasan ni ara ipolongo egbe oselu ni; o se je pe egbe oselu PDP nikan ni gbogbo camera ati oniroyin agbaye n wa kiri. Se PDP nikan lo wa ni Ekiti ni gbogbo wa n irukan niwọn, e sinmi PDP lotun PDP losi; eyin oniroyin ko ki n se egbe kan soso lowa nibe ni oju titemi o e ti ro pe ti e ko ba wole fun ipo yi ohun ti e maa fise evidence pe ejo niyen o ma se o