Got a TV Licence?

You need one to watch live TV on any channel or device, and BBC programmes on iPlayer. It’s the law.

Find out more
I don’t have a TV Licence.

Ìsọníṣókí

  1. Iléèṣẹ́ ọlọ́pà sọ pé àwọn kò rán ọlọ́pà lọ sílé Saraki
  2. Ẹgbẹ́ òṣèlú APC di ẹgbẹ alátakò nílé aṣofin àgbà báyìí
  3. Sẹnatọ mẹ́ẹ̀dógún fi ẹgbẹ́ òṣelú APC sílẹ̀ lọ sí PDP
  4. Àwọn ọlọ́pà dí ẹnu ọ̀nà ilé Bukọla Saraki lówurọ kutu òní
  5. Bakan naa ni wọ́n yii ile ìgbakeji Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Ike Ekweremadu

Jíjábọ̀ ohun tí ń lọ lọ́wọ́

Nípasẹ̀ Busayo Akogun

Gbogbo àkókò tí a kọ jẹ́ ti UK

Eyi ni opin akojọpọ iroyin ti a ti n mu wa fun yin lori bi awọn asofin Naijiria kan se fi ẹgbẹ oṣelu wọn silẹ l'oni.

A lero pe ẹ gbadun wa?

Ẹ maa gbagbe lati maa kan si bbc.com/yoruba fun iroyin lọlọkan ko j'ọkan ni ede Yoruba.

Ẹ ṣe pupọ.

Saraki kó àwọn aṣòfin lẹ́yìn lọ s'ílé Ekweremadu

Aarẹ ile aṣofin, Bukọla Saraki, ti lewaju awọn aṣofin kan lọ sile igbakeji rẹ, Ike Ekweremadu.

Ṣaaju ni awọn ọlọpa yi ile Ekweremadu ka ni òwúrọ̀ òní.

Ọkan lara awọn oluranlọwọ fun Ekweremadu, sọ fun BBC pe, awọn sẹnetọ ati awọn ọmọ igbimọ amuṣẹya ẹgbẹ oṣelu PDP wa lara ikọ̀ tó tẹlé Saraki lọ sile Ekweremadu.

Bukọla Saraki
BBC
Àwọn ọlọpa yi ile Saraki naa ka l'owurọ oni

Fayose ní ìjọba oníkùmọ̀ kò ní ì pẹ́ f'ẹ̀yìn janlẹ̀

Gomina ipinlẹ Ekiti ti yoo fi ipo naa silẹ laipẹ, Ayodele Fayose, ti ni opin ko ni i pẹ de ba ijọba to n lo asẹ onikumọ l'orilẹ-ede Naijiria.

O sọ eyi l'oju opo Twitter rẹ l'oni.

Ọrọ naa to sọ wa ni ibamu pẹlu bi awọn sẹnetọ kan ati awọn ọmọ ile aṣofin kekere ni Naijiria ṣe fi ẹgbẹ to wa ni iṣakoso lọwọ-lọwọ, APC, silẹ l'oni.

Fayoṣe jẹ ẹnikan gboogi to maa n tako iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari.

I see an impending dawn of a new era in Nigeria. I see an impending defeat of tyranny. God bless those patriotic NA… twitter.com/i/web/status/1…

EFCC kọ́we pe igbákejì Saraki, Ike Ekweremadu

Ajọ EFCC ti ransẹ si igbakeji aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Ike Ekweremadu, lati wa sọ t'ẹnu rẹ lori awọn iwadi kan ti wọn ni awọn n ṣe lori ẹsun ìgbìmọ̀ ọ̀tẹ̀, àṣìlò ipò, àti jíjí owó ìlú.

Ọkan lara awọn oluranlọwọ fun Saraki, Bamikole Banks Omisore lo fi aworan lẹta kan sita to sọ pe EFCC kọ si Ekweremadu loju opo Twitter rẹ.

Ṣugbọn, BBC ko le sọ boya ojulowo ni lẹta naa tabi ayederu.

Letter submitted by EFCC on Deputy Senate President this morning.

Letter submitted by EFCC on Deputy Senate President this morning.

Fídíò Bukọla Saraki bó ṣe n fi ilé aṣòfin sílẹ̀

Fidio yii n ṣafihan aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Bukọla Saraki, bo ṣe n fi gbọ̀ngàn ilé aṣofin silẹ̀ lẹyin to so ijoko ile to waye l'ọ́jọ́ kẹrinlelogun, oṣu Keje rọ di ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹsan.

Amugbalẹgbẹ Saraki, Bamikọle Banks Omisore, lo fi fidio naa sita loju opo Twitter rẹ.

Inú mi i dùn sí bí àwọn sẹnetọ kan ṣe fi APC sílẹ̀ - Oshiomole

Alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomole sọ pe inu oun dun pe awọn sẹnetọ kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ́ naa fi ẹgbẹ́ silẹ lọ si PDP.

O sọ bẹ fun awọn akọroyin to wa ni ile aarẹ, lẹyin ipade kan to ṣe pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari l'oni.

O ni 'ẹgbẹ́ oṣelu naa ko ni imọlara bi wọn ṣe fi ẹgbẹ́ silẹ̀, nitori awọn yoo ṣi bori ninu eto idibo 2019.'

Oshiomole
NAN
Adams Oshiomole ni ẹgbẹ́ APC ko mọ̀ ọ́ lára pe àwọn sẹnetọ kan fi ẹgbẹ́ silẹ

Èyí ni orúkọ àwọn sẹnatọ tó fi APC sílẹ̀ lọ sí PDP àti ADC

Dino Melaye (Kogi)

Barnabas Gemade (Benue)

Ibrahim Danbaba (Sokoto)

Shaaba Lafiaji (Kwara)

Ubali Shitu (Jigawa)

Rafiu Ibrahim (Kwara)

Suleiman Hunkuyi (Kaduna)

Isa Misau (Bauchi)

Monsurat Sunmonu (Oyo)

Soji Akanbi

Usman Nafada (Gombe)

Musa Kwankwaso (Kano)

Suleiman Nazif (Bauchi)

Lanre Tejuosho

Abdulaziz Murtala Nyako (Adamawa) - ADC

Díẹ̀ lára àwọn ohun tí ẹ sọ lórí Facebook BBC Yoruba

Àwọn ololufẹ BBC News Yoruba fi eroo ọkan wọn ransẹ si wa lori Facebook lori iṣẹlẹ to n waye nile aṣofin Naijiria.

Diẹ lara wọn niyii:

Oladele AfolabiHmmm iru ijọba wo l'anse l'orileede yii, se ijoba amunisin ni abi ijọba olominira? O toju su mi o!.

Abike FetugaO ma’a se Oo.. Kangun kangun,a kangun si bi kan Oo. Oluwa ko ran Orilẹ-ede Nigeria lọwọ.

Folarin OlatunjiBuhari ti mọ wipe osese ti saraki ba darapọ mọ PDP, ewu nla ni fun oun ati wipe wọn le yọ oun nipo..(Impeachment loading)

Iléèṣẹ́ ọlọ́pà sọ pé àwọn kò dínà mọ́ Saraki

Ileeṣẹ ọlọpa Naijiria ti ni àwọn ko di ọna ile aarẹ ile aṣofin agba, Bukọla Saraki.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpa, Jimoh Moshood, ninu atẹjade kan, sọ pe awọn ko ran ọlọpa kankan lati lọ si ile Bukọla Saraki tabi ti igbakeji rẹ, Ike Ekweremadu.

O fi kun pe dandan ni ki Saraki yọju sileeṣẹ ọlọpa lati wa sọ ohun to mọ nipa idigunjale to waye ni Ọffa.

Bi bẹ ẹ kọ, ileeṣẹ ọlọpa ko ni kuna lati lo agbara ofin lati fi gbe.

Awọn ọlọpa
NIGERIA POLICE
Ileesẹ ọlọpa ni ki i ṣe ootọ l'awọn di ọna mọ Saraki

KókóỌmọ ilé aṣòfin kékeré méjìdínlógójì fi APC sílẹ̀

Ko din ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mejilelgbọn, to wa nile aṣofin kekere, to ti fi ẹgbẹ naa silẹ bayii.

Olori ile aṣofin naa, Yakubu Dogara, lo fi ikede naa sita.

Diẹ lara awọn asọfin naa ni:

Funke Adedoyin

Kabiru Marafa

Garba Ibrahim muhammad

Zakari Muhammed

Lawal Rabiu

Orin orisirisi ni awọn ọmọ ile aṣofin naa n kọ lẹyin ikede Yakubu Dogara.

Dogara sọ wi pe adun to wa nibi oselu tiwantiwa ni ki awọn asoju le yan ẹgbẹ to wu wọn.

Ile asofin kekere
NASS
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mẹtalelọgbọn to wa ni ile aṣofin kekere fi ẹgbẹ́ silẹ.

Inú wa kò dùn sí bí àwọn sẹnatọ kan ṣe fi ẹgbẹ́ sílẹ̀ - APC

Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ti sọ pe inu awọn ko dun si bi àwọn sẹnatọ kan ṣe fi ẹgbẹ naa silẹ, ti wọn si darapọ mọ, PDP.

Agbẹnusọ fun ẹgbẹ naa, Mallam Bolaji Abdullahi, sọ fun BBC pe awọn ti gbiyanju lati ri i pe awọn aṣofin naa ko kuro ninu ẹgbẹ, ṣugbọn, pabo ni igbiyanju naa jasi.

O ni 'àwọn ti ṣetan lati tẹsiwaju ninu irinajo awọn, lẹyin ohun to ṣẹlẹ.'

Ati pe, awọn l'awọn ṣi ni ọmọ ile to pọju lọ ninu ile aṣofin kekere, to fi mọ awọn gomina to pọju ni Naijiria.

Bolaji abdullahi
APC
Inú ẹgbẹ́ òṣèlú APC kò dùn nítorí bí àwọn sẹnatọ kan ṣe fi ẹgbẹ́ nàá sílẹ̀

KókóỌ̀pọ̀lọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilé aṣòfin kékeré ṣetán láti fi APC sílẹ̀

Iroyin to n tẹwa lọwọ bayii ni pe ogunlọgọ awọn ọmọ ile aṣofin kekere Naijiria, ti n buwọlu iwe kan gẹgẹ bi igbesẹ lati kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Ṣaaju ni owurọ oni, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP to wa ni ile aṣofin naa jade sita lati jo, nigba ti wọn gbọ pe awọn ọmọ ile aṣofin agba mẹẹdogun ti fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ bọ si PDP, gẹgẹ bi ẹ ṣe ri i ninu fidio yii.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP n dunnú lórí àwọn sẹnatọ tó fi APC sílẹ̀

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló bẹ ilé aṣòfin àgbà Nàìjíríà wò l'ónì

Ọgba ile aṣofin Naijiria
BBC
Ọpọlọpọ eniyan lo n f'ẹsẹ palẹ ni owurọ oni nile aṣofin agba
Ọgba ile asofin
BBC
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo paapa ko gbẹyin nile asọfin agba
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo
BBC
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo paapa ko gbẹyin nile asọfin agba

Ẹgbẹ́ PDP kí àwọn aṣòfin tó fi APC sílẹ̀ kú oríìre

Ẹgbẹ oṣelu alatako ni Naijiria, Peoples Democratic Party, PDP, ti ki awọn aṣofin agba to fi ẹgbẹ All Progressives Congress, APC silẹ, wa a darapọ mọ PDP.

Agbẹnusọ fun PDP, Kọla Ologbondiyan, lo fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ.

Congratulations to leaders and members of the @OfficialPDPNig , we are the majority in the @NGRSenate . This victo… twitter.com/i/web/status/1…

Díẹ̀ lókù kí wọ́n pa mí - Dino Melaye

Ọkan lara awọn asọfin to fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ, Dino Melaye, ni ara idi ti oun fi ẹgbẹ naa silẹ ni bi wọn sẹ lo awọn oṣiṣẹ eleto aabo lati fiyajẹ oun.

O ni 'diẹ lo ku ki wọn gba ẹmi mi.'

Senator Dino Melaye cites Order 14 and brings to the notice of the Senate his attempted assassination by the Nigeri… twitter.com/i/web/status/1…

APC pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ jànkàn-jánkàn

Ko to o di pe awọn ọmọ ẹgbẹ APC to jẹ aṣofin, fi ẹgbẹ naa silẹ loni, ni ogunlọgọ awọn ọmọ ẹgbẹ ti fi ẹgbẹ naa silẹ, nitori ohun ti wọn pe ni ifiya jẹni.

Diẹ lara wọn ni gomina ipinlẹ Ọṣun nigba kan, Ọlagunsoye Oyinlọla, ati olori oṣiṣẹ fun Saraki, Hakeem Baba Ahmed.

Ami idanimọ ẹgbẹ APC
APC
Igba akọkọ kọ niyi ti awọn ọmọ ẹgbẹ yoo fi APC silẹ

KókóIlé aṣòfin àgbà sún ìjókò sí ọjọ́ mì í

Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Bukọla Saraki, ti so ijoko ile aṣofin to waye l'oni rọ di ọjọ́ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹsan, lẹyin ti awọn aṣofin kan lati inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, fi ẹgbẹ naa silẹ, ti wọn si darapọ mọ ẹgbẹ, Peoples Democratic Party, PDP.

Ohun to ṣẹlẹ yii ti mu ki awọn ọmọ ẹgbẹ osẹlu PDP, pọ ju awọn ọmọ ẹgbẹ́ APC lọ ni ile aṣofin naa.

Àwọn tó n fẹ̀hónú hàn yá bo ilé aṣòfin Nàìjíríà

Awọn kan to n fi ẹhonu han yabo ile aṣofin Naijiria loni.

Asiko ti awọn asofin n se ijiroro wọn ni wọn yabo ibẹ, ti wọn si n sọ pe ki awọn asọfin ṣe iwadi awọn iṣẹlẹ iṣekupani to n waye ni orilẹ-ede Naijiria.

Awọn olufẹhonu han naa to lọ si ile aṣofin Naijiria
BBC

Sẹnatọ mẹ́ẹ̀dógún fi ẹgbẹ́ òṣèlú APC sílẹ̀

Iroyin to n tẹ wa lọwọ bayii ni pe ọpọlọpọ awọn sẹnatọ ti fi ẹgbẹ osẹlu to n ṣe iṣakoso lọwọ ni Naijiria, All Progressives Congress, APC, silẹ.

Aarẹ ile aṣofin naa, Bukọla Saraki lo kede igbesẹ awọn sẹnatọ naa.

Orukọ gbogbo wọn niyii:

Sen. Tejouso

Sen. Shaaba

Sen. Gemade

Sen. Melaye.

Sen. Shittu

Sen. Rafiu

Sen. Shitu Ubali

Sen. Isa Misau

Sen. Hunkuyi

Sen. Monsurat

Sen. Danbaba

Sen. Nafada

Sen. Nazif

Sen. Kwankwaso

Abdul-Azeez Murtala Nyako

Senators that defected from @APCNigeria Sen. Tejouso Sen. Shaaba Sen. Gemade Sen. Melaye. Sen. Shittu Sen. Ra… twitter.com/i/web/status/1…

Senate President, @bukolasaraki announces defection of Senators: @lanretejuoso, Shaaba Lafiagi, @BI_Gemade,… twitter.com/i/web/status/1…

Àjọ EFCC yíì ilé Ekweremadu ká

Àwọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ijẹkujẹ ni Naijiria, EFCC, yii ile igbakeji aarẹ ile aṣofin agba Naijiria, Ike Ekweremadu ka lowur oni.

Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ fun un lori eto iroyin fi idi rẹmulẹ fun BBC pe, ile naa to wa ni adugbo Apo nilu Abuja

Ile Ike Ekweremadu
UCHE ANICHUKWU
Ile Ike Ekweremadu

Àwọn ọlọ́pà yíì ilé Saraki po

Ileeṣẹ ọlọpa Naijiria yii ile Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria po ni owurọ kutu-kutu oni.

Agbẹnusọ rẹ, Bamikọle Omisore fi awọn aworan kan sita loju opo Twitter rẹ pe, awọn ọlọpa di ẹnu ọna ile Saraki.

Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Saraki sọ fun BBC pe, aarọ kutu ni awọn ọlọpa de si ile naa to wa ni adugbo Maitama, lopopona Lake Chad, nilu Abuja.

BREAKING: The @PoliceNG have blocked the Senate President @BukolaSaraki's convoy at Lake chad junction on his way t… twitter.com/i/web/status/1…

Ẹ káàbọ̀ sí BBC Yoruba. À n mú bí nkan ṣe n lọ lórí ìjà òṣèlú tó n wáyé ní Nàìjíríà wá fún yín.