Got a TV Licence?

You need one to watch live TV on any channel or device, and BBC programmes on iPlayer. It’s the law.

Find out more
I don’t have a TV Licence.

Ìsọníṣókí

 1. Òní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kárùn-ún ọdún 2019 ni ètò ìbúrawọlé ń wáyé lórílẹ̀èdè Nàìjíríà
 2. Láàrin ọdún 1999 sí ọdún 2019, ààrẹ mẹ́rin ló ti jẹ ní Nàìjíríà
 3. Ààrẹ Muhammadu Buhari ni ààrẹ ikeeje ati ikẹẹdogun ti orilẹede Naijiria
 4. Awọn gomina ti wọn dibo yan naa n bura wọle lonii
 5. Ko ni ju bayii lọ fun akojọpọ iroyin wa bo 'se n lọ lọwọ-lọwọ, ẹ 'seun ti ẹ ba wa kalọ

Jíjábọ̀ ohun tí ń lọ lọ́wọ́

Nípasẹ̀ Yetunde Olugbenga àti Busayo Akogun

Gbogbo àkókò tí a kọ jẹ́ ti UK

 1. Ó dìgbà kan ná!

  Ẹ̀ ṣeun ti ẹ dara pọ̀ mọ́ wa lónìí fún ìròyìn káàkiri Nàìjíríà níbi tí ètò ìbúrawọlé ti ń wáyé.

  Ẹ máa kàn sí bbc.co/yoruba ní gbogbo ìgbà fún àwn ìròyìn àtìgbà dé ìgbà.

  Látọwọ́ Yetunde Olugbenga àti Busayo Akogun tó ń jábọ̀, a dúpẹ́ púpọ́ lọ́wọ́ yín.

  Ó dìgbà kan ná!

 2. Wo àwọn ààrẹ Nàìjíríà láti 1999 títí d'òní

  Video content

  Video caption: Wo àwọn ààrẹ Nàìjíríà láti 1999 títí d'òní
 3. Sowore: Ìjọba pàṣán ni ìjọba Buhari

  Oludije ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu AAC ninu idibo to kọja ni "bi ẹ ba wo o dadaa, inu awn ọmọ Naijiria ko dun si eto to n lọ lonii".

  Lori pe aarẹ́ Buhari ko sọ̀rọ̀ iburawọle si awọn ọm Naijiria, Omoyele Sowore ni ijọba paṣan ni Naijiria wa yii eyi ti o ta ba ara ile ta ba ara oko".

  O ni aarẹ ko sọrọ tori pe ki lo fẹ sọ to jẹ́ wi pe irọ ni gbogbo rẹ.

  Omoyele Sowore
  Image caption: Atọkun n fọrọ wa Omoyele Sowore lẹnu wo
  Omoyele Sowore
  Image caption: Omoyele Sowore
 4. Ifeanyi Ugwuanyi ti Enugu rèé ní gbàgede ìbúrawọlé

  Ifeanyi Ugwuanyi ti Enugu
  Image caption: Ifeanyi Ugwuanyi ti Enugu
 5. Gomina Dave Umahi ti ìpínlẹ̀ Ebonyi búrawọlé

  Gomina Dave Umahi
  Image caption: Gomina Dave Umahi
 6. El Rufai búrawọlé fún sáà kejì ní ìpínlẹ̀ Kaduna

  Gomina Nasir El Rufai
  Image caption: Gomina Nasir El Rufai
 7. Gómìnà Badaru Abubakar ti ipinlẹ̀ Jigawa bùrawọlé

  Gomina Badaru Abubakar
  Image caption: Gomina Badaru Abubakar
 8. Dapo Abiodun gbàjọba lọ́wọ́ Amosun

  Video content

  Video caption: Nigeria swearing-in: Ètò ìbúrawọlé Dapo Abiodun ní Ogun
 9. Òjò ń pa Sanwoolu!

  Gẹ́lẹ́ ti Gomina tuntun ti ipinlẹ Eko Babajide Sanwoolu gun ori pepele lati burawọle niwaju adajo lojo bẹrẹ si ni bọ́ to bẹẹ̀ ti wọn sare ga agboojo le gomina tuntun lori.

  Babajide Sanwoolu
  Image caption: Babajide Sanwoolu
 10. Awọn àlejò jànkàn-jànkàn l'Abuja

  Lara awọn eekan oṣelu Naijiria ree gẹgẹ bi alejo pataki nilu Abuja nibi eto ibura wọle.

  Ọgagun Yakubu Gowon
  Image caption: Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ ri Ọgagun Yakubu Gowon
  Awọn àlejò jànkàn-jànkàn l'Abuja
  Image caption: Latọwọ osi, Abdulaziz Yari gomina ana ti Zamfara, Yahaya Bello ti Kogi, Rotimi Akeredolu ti Ondo
  Awọn àlejò jànkàn-jànkàn l'Abuja
  Image caption: Latọwọ osi, Adams Oshiomole, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Bisi Akande
 11. Babajide Sanwoolu búrawọlé Eko

  Babajide Sanwoolu
  Image caption: Idile Babajide Sanwoolu
  Babajide Sanwoolu
  Image caption: Idile Babajide Sanwoolu
 12. Igbakeji gomina tuntun nipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan ti bura wọle.

  Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan
  Image caption: Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan
  Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan
  Image caption: Onimọẹrọ Rauf Ọlaniyan
 13. Aarẹ Buhari ko ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lẹyin ibura

  Ni kete ti Aarẹ Muhammadu Buhari burawọle fun saa keji - Aarẹ kan ka ọrọ ibura rẹ ni. Lẹyin naa lo tẹwọ gba asia tuntun lati ṣilẹkun fun saa rẹ keji, to si rin kiri ninu ọkọ ni eto iburawọle naa wa si opin.

  Aarẹ ko wulẹ sọrọ apilẹkọ kankan gẹgẹ bii ti atẹyinwa fun gbogbo aarẹ tabi gomina tuntun ti wọn ba bura fun.

  Aṣe jijuwọ pe o dabọ, o ya nile ni aarẹ ju si awọn ọmọ Naijiria.

  Aarẹ Buhari
 14. Àwọn ará Kwara ni "Idẹra dé"

  Lara awọn esi ẹyin ololufẹ wa rèé lójú opo Facebook bbcnewsyoruba

  Esi awọn ara Kwara
  Image caption: Esi awọn ara Kwara
 15. Abdulrazak Abdulrahman ti Kwara jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú adájọ́

  Video content

  Video caption: Nigeria Swearing in: Abdulrahman Abdulrazak búra wọle bíi gómìnà tuntun ní Kwara
 16. Èrò wọ́ tẹ̀lé Seyi Makinde lọ ibi ìbúrawọlé l'Oyo

  Kẹti kẹti ni ero wọ tẹle amoju ẹrọ Seyi Makinde ati iyawo rẹ lọ si ibi eto iburawọle ni ipinlẹ Oyo

  Seyi Makinde ti Oyo
  Image caption: Seyi Makinde ti Oyo
 17. Ètò ìbúrawọlé ní ìpínlẹ̀ Eko

  Igbakeji gomina ipinlẹ̀ Eko, Obafemi Hamzat, iyawo ati awọn ọmọ rẹ lori pepele iburawọle.

  Igbakeji gomina Eko
  Image caption: Idile Obafemi Hamzat
  Igbakeji gomina Eko
  Image caption: Igbakeji gomina Eko
 18. "Mo ṣèlérí láti fọkàn sin orílẹ̀èdè Nàìjíríà"

  Ààrẹ Buhari rèé tó ń búra níwájú adájọ́ àti gbogbo ọmọ Nàìjíríà

  Video content

  Video caption: Nigeria Swearing-in 2019: Ààrẹ Buhari búrawọlé fún sáà kejì
 19. Alaafin ilu Ọyọ de sibi iburawọle gomina Ọyọ

  Alaafin ilu Ọyọ
  Image caption: Ọba Lamidi Adeyẹmi Kẹta nibi ayẹyẹ iburawọle fun Seyi Makinde
 20. Gbàgede TBS l'Eko ń rọ́ kẹ̀kẹ̀ ní ìgbáradì de ìbúrawọlé

  Gbagede Tafawa Balewa Square ni eto iburawọle ti ipinlẹ Eko yoo ti waye.

  Lọwọ lọwọ, awọn eniyan ti wa nikalẹ ti awọn onilu si n fi ilu ki awọn eeyan kuabọ bi wọn ṣe n wọle si gbagede.

  Bakan naa ni olori ikọ ogun amuṣẹya ro dẹdẹ ni imura ologun ki aabo lee daju nibi eto iburawọle.

  Ipinlẹ Eko
  Image caption: Ipinlẹ Eko
  Ipinlẹ Eko
  Image caption: olori ikọ ogun amuṣẹya
  Ọlọpa Eko
  Image caption: Ọlọpa Eko mura bi asiko ijọba ologun