Got a TV Licence?

You need one to watch live TV on any channel or device, and BBC programmes on iPlayer. It’s the law.

Find out more
I don’t have a TV Licence.

Jíjábọ̀ ohun tí ń lọ lọ́wọ́

Nípasẹ̀ Yetunde Olugbenga

Gbogbo àkókò tí a kọ jẹ́ ti UK

 1. Post update

  Oniyan ṣe e, ọlọbẹ ṣe e, gbogbo ẹyin tẹẹ ba wa fifẹ jẹ ẹ naa ṣeun pupọ.

  Lori gbogbo eto eto idibo ipinlẹ Kogi ati Bayelsa ni Yajoyajo, nihin ni a o fi adagba rẹ rọ si. Ẹ kan si oju opo ayelujara wa, bbcyoruba.com ati facebook wa bbcnewyoruba ka jọ maa tẹsiwaju.

  A o ni jaa yin kulẹ rara.

  Latọwọ Yetunde Olugbenga, Olubayode Alebiosu ati Busola Afolayan tẹẹ ri to ti n jabọ lati bii ọjọ meji o le ati gbogbo akọroyin BBC Yoruba lapapọ, a ni ipade wa bii oyin o!

 2. 'Nítoríi Yahaya la ṣe ń jó là ń yọ̀'

  Báyìí ni àjọyọ̀ ṣe ń lọ ní Kogi láti fi idunu han lori pe gomina Yahaya Bello ni ajọ INEC kede pe o jawe olubori.

  Ajọyọ ni Kogi
  Ajọyọ ni Kogi
  Ajọyọ ni Kogi
 3. Ìran tí Primate Ayodele rí ṣáájú ìdìbò Kogi àti Bayelsa rèé!

  Oluṣoaguntan Ayodele Babatunde ti ìjò INRI bá BBC sọ̀rọ̀ lórí ìran tó rí ṣáájú ìdìbò ìpínlẹ̀ Kogi àti Bayelsa.

  Video content

  Video caption: Kogi vs Bayelsa: Primate Ayodele sọ àsọtẹ́lẹ̀
 4. Yahaya Bello fẹ̀yìn Wada gbo'lẹ̀, ó padà gẹ́gẹ́ bíi gómìnà Kogi

  Ajọ eleto idibo to boju to gbogbo eto idibo to waye ni ipinlẹ Kogi ti kede gomina to ṣi wa lori alefa ni ipinlẹ̀ naa, Yahaya Bello gẹgẹ bi ajawe olubori ninu ibo gomina.

  Ibo 406,222 ni Yahaya Bello to jẹ oludije labẹ asia ẹ́gbẹ oṣelu APC fi fẹyin Musa Wada ti PDP janlẹ ti oun ni ibo 189,704

  Gomina Yahaya Bello n ṣe ajọyọ
 5. Àjọ INEC ń kó èsì pọ̀ ṣáájú ìkéde gómìnà tuntun

  Ajọ INEC Kogi
  Ajọ INEC Kogi
 6. Àjọ INEC so ìbò kíkà ní ìpínlẹ̀ Kogi rọ̀ dí aago mẹ́sàn án àárọ̀ ọjọ́ Ajé

  Musa Wada ati Yahaya Bello

  Kii dun ko pọ, ṣoki bayii ni ọbẹ oge, Ajọ eleto idibo INEC ti fi adagba ibo kika nipinlẹ Kogi rọ di aago mẹsan an aarọ ọjọ Aje.

  Esi ijọba ibilẹ meji loku ti INEC yoo fi ka gbogbo esi ibo ipinlẹ Kogi tan bayii.

 7. Èsì láti Kogi

  Bi Bayelsa ṣe gberasọ pẹlu ikede, ti Kogi naa ṣi n lọ lọwọ

  Ankpa

  APC: 11269

  PDP: 28108

  SDP:399

 8. Ìpínlẹ̀ Bayelsa ti bẹ̀rẹ̀ ìkéde èsì ìdìbò gómìnà

  Lẹyin ọpọlọpọ wakati ti awọn ọmo Naijiria ti n reti, ajọ eleto idibo ipinlẹ Bayelsa ti bẹrẹ si ni kede awọn esi idibo wọn ni sisẹ n tẹle.

  Ṣaaju ni wọn ti fi ikede sita pe aago mẹsan owurọ ni ikede yoo gberasọ ṣugbọn bẹẹ kọ lo ri tori wipe nkan bi aago mẹrin irọlẹ ni wọn pada bẹrẹ ikede.

  A n se akojọpọ ẹkunrẹrẹ iroyin yajoyajo lọwọ, a o maa gbe ẹkunrẹrẹ iroyin naa sori atẹ iroyin wa laipẹ. Ẹ jọwọ, ẹ tun oju opo iroyin yi yẹwo, ki ẹ lee ri ẹkunrẹrẹ iroyin ọtun laipẹ.

  Ajọ eleto idibo Bayelsa
 9. PDP fa àjọ INEC létí ní Kogi

  PDP kọ èsì àwọn ìdìbò tí wọ́n fura sí ní Kogi

  Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ni ipinlẹ Kogi ti ki ajọ eleto idibo nikilọ lori awọn esi idibo kọọkan ti wọn ni awọn fura si pe wọn gbe lati ilu Okene lọ si atawọn apa ibomii lati ran ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lọwọ.

  Nitorinaa, PDP ni awọn n fẹ ki wọn wọgile awọn iru ibudo bẹẹ ni kiakia paapaa ni ijọba ibilẹ Okene.

  Ẹgbẹ naa ninu ọrọ ti alukoro wọn, Kola Ologbondiyan fi sita ni ko sẹni ti yoo fẹ gba esi idibo ti wọn yi pada lati ran ẹgbẹ alatako lọwọ. Wọn si kilọ fun ajọ INEC lati ma ṣe kede iru iyipada idibo bẹẹ.

  Ami idanimọ ẹgbẹ PDP