Awọn abọde Libya: Ipinlẹ Ọsun tẹwọgba eniyan mọkanla

Awọn ọmọ ilẹ Naijiria ti wọn ko wale lati Libya Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Awọn ti o pada wale lati Libya pada funra wọn

Ijọba ipinlẹ Ọsun ti tẹwọ gba awọn mọkanla to jẹ̀ ọmọ ipinlẹ naa ti wọn sẹsẹ de lati ilẹ Libya. Ajọ to nmojuto isẹlẹ pajawiri nilẹ wa (NEMA), ati ajọ to ngbogun ti iwa fifi eniyan sowo kotọ lorilẹede Naijiria (NAPTIP) lo seto bi wọn se ko wọn pada wa sile.

Lọjọ ẹti lawọn abọde ilẹ Libya naa de sorilẹede Naijiria ki wọn to gbe wọn wa si ilu Osogbo ni ọjọ aje.

Nigba to nba awọn oniroyin sọrọ nilu Osogbo, oludari eto gbogbo nileesẹ to nmojuto isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Ọsun, onimọẹrọ Akin Adetubẹru salaye wipe obinrin mẹsan ati ọkunrin meji pẹlu ọmọ osu mẹta kan wa lara awọn ti wọn tẹwọgba.

Onimọẹrọ Akin Adetubẹru sọ wipe gomina Rauf Arẹgbẹsọla ko yee kominu lori ipo alaafia awọn ọmọ ipinlẹ naa to wa loke okun wa nigba gbogbo.

O wa gba awọn eeyan ipinlẹ Ọsun to ba nwa ibi ti ọbẹ gbe sọ lọ si oke okun lati maa tọ ilana gbogbo to ba ofin mu.

O ni isoro ti o doju kọ awọn eeyan ti wọn sẹsẹ ko pada lati ilẹ Libya naa kuro ni kekere nitori aisi iwe irinna to pe lọwọ wọn.

Ọkan lara awọn abọde ilẹ Libya naa, arabinrin Jimoh Aisha to jẹ ọmọ bibi ilu Ikirun ni "ohun oju ri kọja sisọ atipe iya to jẹ wọn ju eleyi ti wọn sa fun nile lọ."

Kọmisọna fọrọ ere idaraya ati eto amuludun, ọgbẹni Biyi Ọdunlade ni ijọba ipinlẹ Ọsun ti seto gbogbo fun itọju awọn eeyan naa ati pe awọn ayẹwo to tọ nlọ lọwọ lati yanju idanimọ wọn.