Ẹgbẹ oselu PDP, APC nforigbari lori ọrọ idibo sijọba ibilẹ

Eto idibo fun ijọba ibilẹ ni orile Naijiria maa n ni awuyewuye Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Eto idibo fun ijọba ibilẹ ni orile Naijiria maa n ni awuyewuye

Ẹgbẹ oselu Peoples Democratic Party, PDP pẹlu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọsun ti nsọko ọrọ ransẹ si arawọn bayii lori eto idibo sijọba ibilẹ to nbọ lọna nipinlẹ naa.

Ọjọ kẹtadinlogun osu kinni ọdun 2018 ni ijọba ipinlẹ Ọsun fi idibo naa si, sugbọn awuyewuye nwaye lori bi ileẹjọ giga kan nilu Abuja se gbe asẹ daaduro na le eto idibo ọhun titi di igba ti ipẹjọ to nlọ lọwọ lori ibo naa yoo fi yanju.

Amọsa, alaga igun kan ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ naa, Soji Adagunodo ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ẹgbẹ oselu PDP lati tẹsiwaju pẹlu idibo naa lainaani asẹ ti ileẹjọ gbe kalẹ lori rẹ.

Ọgbẹni Adagunodo wipe ohun ti ẹgbẹ oselu APC nkede ni pe oun ga ju ofin lọ eleyi to ni o "sajeji si eto isejọba ati oselu."

O fi kun-un wipe" isọwọ sare ijọba ipinlẹ Ọsun labẹ akoso gomina Rauf Arẹgbẹsọla lori ọrọ idibo si ijọba ibilẹ naa, lainaani asẹ ileẹjọ, nmu ifunra dani."

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ oselu PDP, APC nforigbari lori ọrọ idibo sijọba ibilẹ

Nigba to nfesi si ọrọ ti alaga ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọsun sọ, oludari eto ipolongo fun ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọsun, amofin Ọyatomi ni ẹbi ẹgbẹ oselu APC kọ ni pe idibo naa yoo tẹsiwaju nitori, ẹgbẹ oselu jakejado agbaye kọ ni nseto idibo biko se ajọ ti wọn gbe kalẹ lati seto irufẹ idibo bẹẹ.

Oludari eto ipolongo lẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọsun naa salaye siwaju wipe "eto isejọba ti ipinlẹ Ọsun fẹ la kalẹ lẹka isejọba ibilẹ kii se tuntun si eto oselu oruilẹede Naijiria ati wipe, ilana ti apapọ orilẹede Naijiria lo lasiko isejọba oselu akọkọ ni."

Ẹjọ nlọ lọwọ lori boya eto idibo ijọba ibilẹ naa yoo le wale lẹyin ti wọn ti fa ijọba ipinlẹ Ọsun ati ajọ eleto idibo ipinlẹ naa lọ sileẹjọ lori boya o lẹtọ ;lati seto idibo naa tabi bẹẹkọ.

Related Topics