Ileesẹ aarẹ Naijiria: 'Ko sọrọ lori lẹta Ọbasanjọ'

Aarẹ Ọbasanjọ pẹlu aarẹ Buhari Image copyright Buhari/Twitter
Àkọlé àwòrán Aarẹ Ọbasanjọ ni nkan o rọgbọ fun araalu labẹ isejọba Buhari

Ileesẹ aarẹ ilẹ Naijiria ti salaye wipe awọn ko ni ọrọ kankan lati sọ si lẹta ti aarọ ana, Olusẹgun Ọbasanjọ kọ ninu eyi ti o ti bu ẹnu atẹ lu isejọba aarẹ Buhari.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC Yoruba, agbẹnusọ fun aarẹ, Ọgbẹni Shehu Garuba sọ pe "ko sọrọ".

Aarẹ ana, oloye Olusẹgun Ọbasanjọ salaye ninu lẹta rẹ naa wipe ara awọn nkan ti ko dẹrun labẹ isejọba Buhari ni iwa ẹlẹyamẹya, aini oye to kuna lori eto oselu abẹnu gẹgẹbii ara awọn iwa to ndoju kọ isejọba to wa lorilẹede yii bayii.

Oloye Ọbasanjọ ko sai tun mu ẹnu kan gulegule awọn darandaran fulani to ni wọn npa ọpọ eniyan lorilẹede Naijiria laisi ẹni to n yẹ wọn lọwọ wo.

Aarẹ ana naa tun sọrọ lori bi aarẹ Buhari se nkuna lati ko awọn ọmọ igbimọ rẹ ni ijanu, leyi to ni o nfi ara jọ bi ẹnipe " iwa ẹlẹyamẹya ti njẹ gaaba lori ilọsiwaju orilẹedeyii lapapọ."

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn eniyan kan ti fi ẹsun kan aarẹ Buhari pe ijọba rẹ ko dan mọọran

Lori bi awọn eniyan kan se nrọọ lati dije fun ipo aarẹ lẹẹkansi, Ọbasanjọ rọ Buhari lati ja kainkain bọ eti si iru awọn arọwa bẹẹ. O ni, asiko ti ẹyẹ ati iyi ba pọ lo yẹ lati sọ kalẹ lori ẹsin atipe, ko si aniani wi pe itan ilẹ Naijiria yoo sọ rere nipa aarẹ Buhari.

"mo kan ngba arakunrin mi, Buhari niyanju ni lati lọ ree sinmi lasiko yii, paapaajulọ pẹlu ọjọ ori rẹ. Adura ni mo n gba fun-un lati lee lo isnmi rẹ lẹyin isẹ ilu ninu ilera to gba muse. Bi o tilẹ jẹ wipe kii se dandan ki aarẹ Buhari gba amọran mi sugbọn o di dandan ki orilẹede Naijiria o tẹ siwaju."

Bakanna ni aarẹ tun salaye wi pe, bi nkan se nlọ laarin ẹgbẹ oselu mejeeji to lamilaaka ju nilẹ Naijiria, iyẹn APC ati PDP, a fi ki a da ajọ ajọ orilẹede Naijiria eleyi ti gbogbo awọn ọmọ orilẹede Naijiria lee darapọ mọ.

Aarẹ Buhari se ipade pajawiri ranpẹ pẹlu Tinubu

Image copyright MUHAMMADU BUHARI/TWITTER
Àkọlé àwòrán Asiwaju Bola Ahmed Tinubu jẹ ogbontarigi oloselu ti o se atilẹhin fun aarẹ Buhari ninu eto idibo ọdun 2015

Awọn olori ẹgbẹ oselu All Progressives Congress (APC) pataki meji, Bola Tinubu ati Bisi Akande se ipade ranpẹ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari ni ibugbe ile-iṣẹ rẹ ni ilu Abuja.

Ibẹwo ti awọn olori ẹgbẹ oselu meji waye wakati diẹ lẹhin ti aarẹ ana, oloye Olusegun Obasanjo ti fi ọrọ kan fun Aarẹ Buhari pe ki o ma gbe apoti idibo ni ọdun 2019 nitoripe o ti kuna lati fi awọn ireti ṣe.