Carabao Cup;Manchester City yege fun asekagba labe Pep Guardiola

Adari egbe agbaboolu Manchester City, Pep Guardiola ti fi idunnu re han nigba ti Manchester City yege fun asekagba idije Carabao Cup leyin ti won na egbe agbaboolu Bristol City pelu amin ayo meta si meji.

Manchester city ti o ti leke lati ibeere pelu amin ayo meji si eyokan latowo Leroy Sane, Sergio Aguero ati Kevin de Bruyne lori papa Ashton Gate.

Iroyin fi lede wipe egbe agbaboolu Manchester City je gaba ninu idije na, eleyi ti o fun won laye lati yege pelu amin ayo meta si meji ninu idije na. Guardiola si ti fi idije na wo igbaradi awon agbaboolu re ati lati fi awon to yanju lara awon agbaboolu re, eleyi tio mu ki won bu ewuro soju Newcastle ninu idije Premier League lopin ose to koja.

Adari egbe agbaboolu to je omo metadinlaadota ti gba ife eye merinla nigba ti o ti dari iko egbe Barcelona, o si gba ife eyemeje pelu agbaboolu Bayern Munich, ti o si n reti lati dari iko egbe Manchester City lati gba ife eye carabao, premier league ati ife eye fa cup.

Ti a ko ba gbagbe, oiko liverpool ni kan lo bu ewuro soju won ni gbogbo idije won ni saa yi. manchester city yio koju cardiff city ninu idije facup lopin ose, nigba ti bristol city yio ma koju qpr ninu idije premier league lojo satide.