Fayose koro oju si Buhari lori pipa awọn Fulani

Gomina Ayọ Fayose ati Aarẹ Muhammadu Buhari
Àkọlé àwòrán,

Gomina Ayọ Fayose ati Aarẹ Muhammadu Buhari ti di sonso meji ti kii fi oju ko oju lori ọrọ ilu

Gomina ipinlẹ Ekiti, Ayọdele Fayọse ti bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Muhammadu Buhari fun ohun to pe ni iha "kokanmi" ti o n kọ si ọkan-o-jọkan ipaniyan to n lọ kaakiri orilẹede Naijiria.

Fayose ni asiko to fun Aarẹ Buhari lati bẹrẹ si nii hu iwa bii aarẹ gbogbo-gboo ilẹ Naijria dipo bii aarẹ ẹya kan soso.

Àkọlé àwòrán,

Ipaniyan kaakiri Naijiria ti sọ ọpọ sinu ibanujẹ

Ninu ọrọ kan to tẹ ransẹ si ori ikanni ayelujara twitter rẹ, Gomina Fayose ni lootọ iwa buruku to buru jai ni pipa ti wọn pa awọn Fulani meje kan ni ilu Gboko ni ipinlẹ Benue, eyi to ni ko see fi ọrọ meji juwe ju wipe iwa ti ko see maa fi ọwọ ra lori ni.

"Iha kokanmi ti Aarẹ Buhari n kọ si gbigbe igbesẹ to tọ lati dẹkun awọn isẹlẹ ipaniyan to n waye ni ipinlẹ Benue ati awọn ipinlẹ miran latọwọ awọn darandaran Fulani lewu pupọ fun ibagbepọ alaafia awọn ọmọ orilẹede Naijria."

O salaye siwaju sii wipe asiko to fun Aarẹ Buhari lati gbe igbesẹ to tọ ni kiakia!

Ohun ti Fayose sọ si Buhari

"Nkan buruku gbaa ni pipa ti wọn pa awọn fulani meje ni ilu Gboko nipinlẹ Benue.

Iha kokanmi ti Aarẹ Buhari n kọ si gbigbe igbesẹ to tọ lati dẹkun awọn isẹlẹ ipaniyan to n waye ni ipinlẹ Benue ati awọn ipinlẹ miran latọwọ awọn darandarn Fulani lewu pupọ fun ibagbepọ alaafia awọn ọmọ orilẹede Naijria.

Asiko to fun aarẹ lati gbe igbesẹ to tọ ni kiakia!"

Kini ileesẹ aarẹ sọ?

Nigba ti BBC Yoruba kan si ileesẹ aarẹ lori ẹsun iha kokanmi ti gomina Fayose fi kan Aarẹ Buhari, agbẹnusọ fun ileesẹ aarẹ Shehu Garba ni ko 's'ọ̀rọ!'

"Ti o ba ti jẹ wipe Fayose lo sọrọ a kii fẹ fesi. Nitorina a o ni ohunkohun lati sọ sii."