Tinubu: Emi ko mọ nipa ipẹtusaawọ APC ti Buhari ni kin se

Tinubu n ki Buhari Image copyright @MBuhari
Àkọlé àwòrán Tinubu ni baba isalẹ fun Buhari lati di aarẹ lọdun 2015

Gẹgẹbi ara ọna lati da alaafia ati isọkan, to n dabi ẹni pe o n fi ẹgbẹ oselu APC silẹ, Aarẹ Muhammadu Buhari ti yan agba ọjẹ kan lẹgbẹ oselu, Asiwaju Bọla Ahmed Tinubu lati lewaju igbesẹ fun atunto ati isọkan l'ẹgbẹ oselu naa.

Iroyin kan to faharan lori opo ikansiraẹni tuwita ti ileesẹ aarẹ Naijiria fisita salaye wipe Aarẹ Buhari yan asiwaju Bola Tinubu lati se aayan ijiroro, ifinukonu, ati irapada igbẹkẹle awọn ọmọ ẹgbẹ ninu isọkan ẹgbẹ oselu naa.

Kii se iroyin mọ wi pe lẹnu lọọlọọ yii, nkan o rọgbọ fun ẹgbẹ oselu APC pẹlu oniruru iroyin nipa edeaiyede, ẹhonu ati ibinu awọn igun kan ati eeyan kan lẹgbẹ oselu naa.

Lara isẹ tuntun ti wọn gbe le Tinubu lọwọ yii, ni pipẹtu si aawọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oselu naa, ati laarin awọn asiwaju ẹgbẹ pẹlu awọn to di ipo oselu mu nibẹ.

Ko ti han faye ọna ti Asiwaju Tinubu yoo gba mu isẹ yii se tabi awọn ti yoo ko mọra fun isẹ yii, sugbọn ohun ti awọn eeyan n sọ nipe eyiun bi awọn iroyin to n lọ kaakiri ba see gbagbọ, Tinubu funrarẹ naa ni awọn ẹhonu kan si ẹgbẹ oselu yii, tawọn eeyan si n beere pe tanni yoo tan ẹhonu tirẹ?

"Gẹgẹbii ara igbesẹ to n lọ lọwọ lati tubọ mu ilọsiwaju ba isọkan laarin ẹgbẹ oselu All Progressive party, APC, Aarẹ Buhari ti yan Asiwaju Bola Ahmed Tinubu lati dari awọn eto ijiroro, ifinukonu ati dida igbẹkẹle awọn ọmọ ẹgbẹ naa pada."

Kini Tinubu sọ?

Nigba ti BBC Yoruba kan si ọgbẹni Tunde Rahman to jẹ agbẹnusọ fun Asiwaju Bọla Tinubu lori ọrọ yii, o ni ileesẹ aarẹ ko tii pe Tinubu gan an lati salaye isẹ tuntun yii fun.

"Ori iwe iroyin la ti n ka iroyin yii sugbọn ni kete ti ileesẹ aarẹ ba ti kan si Asiwaju Tinubu, a o sọrọ lori rẹ"

Kini awọn onwoye ri si igbesẹ yii?

Agba akọroyin kan, to tun jẹ alẹnulọrọ ninu ọrọ gbogbo to n lọ, Lasisi Olagunju ni, igbesẹ naa ko jọ eyi to lee so eso rere pẹlu bo se jẹ wipe tinubu funrarẹ gan ni ẹhonu.

O ni 'iwa ibajẹ ni igbesẹ naa jẹ fun aarẹ lati maa lo irinsẹ ijọba lati mojuto aawọ ẹgbẹ oselu rẹ ati pe lai fọtape, igbesẹ yii ti kuna ko to tilẹ gberasọ'

Image copyright @APCNigeria
Àkọlé àwòrán Ọpọ awọn to darapọ mọ ẹgbẹ oselu APC saaju idibo 2015 lo ti n kun fun idi kan tabi omiran

Ileesẹ aarẹ si ni isẹ lati se lori sise idamọ awọn to ni ẹhonu ati awọn ti yoo lewaju eto ipẹtu si aawọ yii, igbayi gan an ni a to lee mọ boya Tinubu gan lo tọ si lati lewaju eto ọhun.

Gbogbo wa la mọ wipe ni ẹkun iwọ oorun gusu ilẹẹwa, APC o si ni ọkan. Se Tinubu ni yoo lọ maa bẹ awọn ọmọlẹyin rẹ tẹlẹ ti wọn ti jaa ju silẹ ni abi awọn lo maa bẹ Tinubu?

"Aarẹ gan lo yẹ ko gbe igbesẹ lori pipẹtu si aawọ gbogbo lẹgbẹ oselu naa. Mi o ni tan yin, ko si aawọ kan bi alara lẹgbẹ oselu APC, ohun to wa nilẹ nibẹ ni ikunsinu awọn ọmọ ẹgbẹ si iha kokanmi ti aarẹ Buhari kọ ati bo se n ta kete si ẹgbẹ oselu naa. ọna kan ti aarẹ si le gba pari aawọ ẹgbẹ oselu yii ni ki oun pẹlu yi iwa ati ise rẹ pada."