Babangida: Agbẹnusọ nbeere biliọnu kan naira lọwọ ọlọọpa

Kassim Afegbua, agbẹnusọ ajagunfẹ́yinti Ibrahim Babangida Image copyright Kassim Afegbua
Àkọlé àwòrán Afegbua ni ileesẹ ọlọpa n tẹ ẹtọ oun loju mọlẹ

Ọgbẹni Kassim Afegbua to jẹ agbẹnusọ fun aarẹ ologun tẹlẹ ni ilẹ Naijiria, Ibrahim Babangida ti pẹ ileesẹ ọlọpa lẹjọ lori titapa si ẹtọ rẹ labẹ ofin.

Ọgbẹni Afegbua, ti ileesẹ ọlọpa kede pe wọn nwa, lo ti pe alukoro ileesẹ ọlọpa, Jimoh Moshood ati awọn ileesẹ iroyin meji mii lẹjọ ibanilorukọ jẹ

Agbẹjọrọ fun ọgbẹni Afegbua, Kayọde Ajulọ, lo pe ẹjọ yii nile ẹjọ giga apapọ kan nilu Abuja lọsan ọjọ isẹgun.

Lara awọn nkan ti wọn n beere fun ni fifopin si bi ileesẹ ọlọpa se n dun mọhuru mọ Afegbua.

Bakanna ni amofin Ajulọ tun ko ileesẹ mohunmaworan apapọ Naijiria, NTA ati channels pọ mọ awọn ti yoo jẹjọ pẹlu ileesẹ ọlọpa.

Ọgbẹni Afegbua gbe atẹjade kan jade lọjọ aiku lorukọ aarẹ Babangida, ninu eyi to ti bu ẹnu atẹ lu isejọba Aarẹ Muhammadu Buhari.

Lati igbayii wa si ni ileesẹ ọlọpa ti kede orukọ rẹ gẹgẹbi ẹni ti wọn nwa ni kiakia pẹlu ẹsun pe o gbe ayederu iroyin sita.