Ijamba ọkọ ran eeyan mẹjọ lọ srun lopopona marosẹ Ibadan si Eko

Ọkọ agbepo to n jona Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn eero inu ọkọ akẹru lo ku ninu isẹlẹ naa

Ko din ni eeyan mẹjọ to padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ ajagbe ejo kan to waye lopopona marosẹ Eko si Ibadan lọjọ isẹgun.

Iroyin sọ wipe awọn eeyan mẹjọ ọhun ku nigba ti ọkọ agbepo kan ati ọkọ akẹru kan kọlu ara wọn, ti ọkọ agbepo naa si gbinna.

Alukoro ileesẹ ẹsọ oju popo nipinlẹ Ogun, Babatunde Akinbiyi salaye wipe, ina sẹyọ lara ọkọ agbepo ọhun ni kete ti ọkọ akẹru naa kọlu u.

O ni, "eeyan mẹjọ ni a ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ti jalaisi ninu isẹlẹ naa nitori wọn jona guruguru ni.

Awọn to fara kaasa iku ninu ijamba naa jẹ awọn ero inu agba ikẹrusi taa mọ si container, to dabi ọkọ akẹru naa.