Buhari: Ẹ mu awọn darandaran to ba n gbe'bọn

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari ni ko saaye ipaniyan fawọn darandaran mọ

Aarẹ Muhammadu Buhari ti orilẹede Naijiria pasẹ fun awọn agbofinro lati maa fi panpẹ ofin gbe ẹnikẹni ti wọn ba ba ibọn lọwọ rẹ lai gba asẹ lati lo ibọn.

Bakanaa ni Aarẹ Buhari tun paroko ikilọ ransẹ sawọn eeyan to n se atọkun ikọlu ati ipaniyan gbogbo kaakiri orilẹede Naijiria, papajulọ awọn darandaran Fulani to wa nidi ikọlu ipaniyan to waye nipinlẹ Benue laipẹ yii.

Aarẹ Buhari se ikilọ yii lasiko abẹwo rẹ si ipinlẹ Nasarrawa to wa lẹkun ila oorun ariwa orilẹede Naijiria.

Aarẹ Buhari ni isejọba oun n sisẹ kikankikan lati dẹkun dukuu to n waye laarin awọn agbẹ ati Fulani lawọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria atipe ijọba ko ni faaye gba ipaniyan labẹ idi yoowu to lee jẹ.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán ireti ọpọ ọmọ Naijiria fun igba pipẹ ni lati ri Aarẹ Buhari jade sita gbangba tako ikọlu awọn darandaran fulani to ti n di lemọlemọ

"Ijọba ko ni faaye gba ikọlu awọn darandaran fulani ati janduku mọ. Gbogbo awọn agbegbe ti ina ikọlu yii ti n ru ni a ti fi awọn agbofinro ransẹ si lati seto alaafia."

Bakannaa ni Aarẹ Buhari tun rọ awọn ti wọn fara kaasa ikọlu naa lati mase gbẹsan.

Image copyright @NGRPresident
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari tun se ifilọlẹ ipese eto ilera alabọde latọwọ awọn majẹobajẹ CHIPS

"Mo gba gbogbo ọmọ Naijiria nimọran wipe ki wọn jinna si igbesẹ gbigba ẹsan nitori asẹ ti wa lọwọ awọn agbofinro lati fi ofin gbe ẹnikẹni ti wọn ba ba ibọn tabi ohun ija oloro yoowu lọwọ rẹ, ki wọn si fi jofin."

Aarẹ Buhari gunle abẹwo lọ si ipinlẹ Nasarawa nibi to ti se ifilọlẹ eto awọn majẹobajẹ ilera alabọde, CHIPS atawọn akanse isẹ kan nibẹ.

Related Topics