WAFU: Falcons gbera lo si Abidjan

Iko agbabọọlu obirin orilẹẹde Naijiria, Super Falcons.
Àkọlé àwòrán,

Odu ni iko agbabọọlu obirin orilẹẹde Naijiria, Super Falcons, nibi idije bọọlu nile Afrika

Ikọ agbabọọlu obirin Super falcons torilẹede Naijiria ti gbera lo si Cote'divoire lati kopa ninu idije fun ife ẹyẹ WAFU ti yoo bẹrẹ lojọru.

Olukọni tuntun fun ikọ Falcons,Thomas Dennerby ni yoo dari ikọ naa pẹlu iranlowo Wemimo Mathew ati Maureen Madu.

Awọn agbabọọlu Super Falcons yoo waako ninu ifesewonse akọkọ ninu idije ife ẹyẹ WAFU, ikẹjo iru rẹ, pẹlu akẹgbẹ wọn lati orilẹẹde Benin lojọbo.

Leyin igba naa, ni wọn yoo tun koju ẹgbẹ agbabọọlu orilẹede Senegal lọjo kẹtadinlogun ati akẹẹgbẹ wọn lati Togo lọjọ kọkandilogun osu keji ọdun2018.