Idibo 2019: Ọmọ Naijiria tabuku bawọn ọmọde se n dibo

Ọmọde kan toun dibo Image copyright @inecnigeria
Àkọlé àwòrán Ọpọlopọ ẹlẹgbẹjẹgbẹ awujọ ju oko ọrọ sajọ Inec lori ẹsun bawọn ọmọde se n dibo

Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria ti salaye wipe awọn ọmọde lanfaani lati dibo lẹkun ariwa orilẹede yi nitori idunkukulaja tawọn osise ajọ INEC n koju lati ọwọ awọn eniyan agbegbe ariwa ilẹ yi..

Oludari ẹka eto ipolongo ati ilanilọyẹ fawọn oludibo labẹ ajọ Inec, ogbẹni Oluwole Osaze-Uzzi lo se alaye ọrọ yi lasiko ifọrọwanilẹnu wo pẹlu ileesẹ amohunmaworan kan, eyi to ti n mu awuyewuye lọwọ latọdọ awọn araalu.

Eyi lo mu ki ikọ iroyin BBC Yoruba tọ eekan kan ninu ẹgbẹ oselu PDP, Ọgbeni Diran Ọdẹyẹmi lọ, lati mọ ero rẹ lori isẹlẹ yi.

Ninu ọrọ rẹ, Ọdẹyẹmi salaye pe ohun itiju gbaa ni ẹsun wipe awọn ọmọde lanfaani ati dibo lẹkun ariwa orilẹede yi.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

O tesiwaju wipe isẹlẹ naa duro gẹgẹ bii ohun abuku fun ilẹ wa lode agbaye, bakanaa si lo tun ta ẹrẹ si asọ ala isejọba awa ara lorilẹede yi.

Image copyright TWITTER/NAHURWEM
Àkọlé àwòrán Awọn alẹnulọrọ ti tako bawọn ọmọde se n dibo lẹkun ariwa orilẹede yi

Ọdẹyẹmi se afikun rẹ wipe bi ẹnikẹni ko ba tako iwa ibajẹ naa, o seese kawọn olugbe ẹkun ariwa ilẹ Naijiria bẹrẹ si ni lo awọn maalu feto idibo.

Ikọ iroyin wa gbiyanju lati ba agbenusọ ẹgbẹ oselu APC, ọgbẹni Bolaji Abdullahi sọrọ lori awuyewuye naa, sugbon gbogbo ẹrọ ibanisọrọ rẹ lasiko ti a n se akojọpọ iroyin, yi ni ko lọ.