Alhasan: Mama Taraba gba fọ́ọ̀mù ipò gómìnà lẹ́gbẹ́ UPD

Aisha Alhasan

Oríṣun àwòrán, @officialAlhasan

Àkọlé àwòrán,

Taraba: mínísítà fún ọ̀rọ̀ obinrn ti kọwe fiṣẹ́ silẹ̀

Sẹnetọ Aisha Alhasan, ti gbogbo ènìyàn mọ si Mama Taraba, to kọwé fipò sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi mínísítà lábẹ́ ìjọba ààrẹ Muhammadu Buhari ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu miran, UDP.

Koda Alhasan ti gba fọọmu lẹgbẹ osẹlu naa bayii lati dije fun gomina ni Ipinlẹ Taraba lọdun 2019.

Lẹyin to fẹgbẹ APC silẹ lo ṣepade pẹlu awọn oniroyin nibi ti o ti sọ pe idi abajọ ti oun fi kuro ninu APC nipe ẹgbẹ naa ko rinlẹ mọ nipinlẹ Taraba.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Kola Ologbodiyan: Jẹgudu jẹra ni ijọba APC

Bakanna, Alhasan sàlayé pé, inú òun bàjẹ́ gidigidi pẹ̀lú ọwọ́ ti ẹgbẹ APC fí mú òun.

O ni gbogbo ìgbésẹ̀ oun nínú ẹgbẹ APC kò ṣe òkunkùn sí ààrẹ Buhari ati bí oun ṣe tọrọ ààyè láti dupò gómìnà nípínlẹ̀ Taraba, sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti rí pé, ẹgbẹ́ APC gbégi dínà fún òun láti díje dupò gómìnà lábẹ́ ẹgbẹ òṣèlú APC.

Oríṣun àwòrán, @officialAlhasan

Àkọlé àwòrán,

Mama Taraba fẹgbẹ́ òṣèlú APC sile

Alhassan wa dupẹ gidigidi lọ́wọ àarẹ Buhari fún àtìlẹ̀yìn rẹ̀ làsìkò tí wọn jọ ṣiṣẹ́ pọ̀ àti oree ọ̀fẹ́ tí òun rí láti sin ará ìlú, bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ igbákejì ààrẹ, Ọjọgbọn Yemi Osinbajo.

Aawọ APC Kaduna: Gomina wo ile Sẹnatọ

Ninu iroyin miran ẹwẹ, Sẹnatọ kan lati inu ẹgbẹ oselu APC, Suleiman Hunkuyi sọ wipe ile oun ni olu ile ẹgbẹ oselu APC ti gomina Nazir El-Rufai wo lulẹ nilu Kaduna, to si ni oun ti dariji.

Hunkuyi sọrọ yi nigba to nba awọn akọrọyin sọrọ, pẹlu afikun pe aarọ ọjọ isẹgun ni gomina El-Rufai lewaju awọn osise wolewole to wo ile ohun palẹ, eyi to sọ pe wọn n lo fun ibujoko igun ẹgbẹ oselu APC kan to wa ni agbegbe Sambo, ni Kaduna.

Oríṣun àwòrán, El-Rufai/Twitter

Àkọlé àwòrán,

Igun APC kan fẹsun asemase ninu ẹgbẹ oselu kan Gomina El-Rufai

Ninu ọrọ rẹ, Senatọ naa wipe ibatan ati ọrẹ oun ni gomina naa jẹ, ati wipe ohun ti dariji Gomina to wo ohun ini oun.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

El Rufai ni onidan lawọn to ni ki oun lọ joko sile ninu APC

Lọse to kọja, awọn igun APC to yapa kan, lo ile ti wọn wo naa, lati kede pe ki gomina El-Rufai lọ rọọkun nile na fun osu mẹfa lori ẹsun pe o se asemase ninu ẹgbẹ oselu APC.

Gomina El-Rufai ninu idahun rẹ si ikede naa sọ̀ pe, igbesẹ naa ko lẹsẹ nlẹ, ati wipe onidan ni igun to yapa kuro ninu ẹgbẹ oselu toun nse adari fun nipinlẹ Kaduna.

Bakan naa, Sẹnato to n soju ẹkun aarin gbungun ipinlẹ Kaduna, Shehu Sani ti fẹjọ gomina Kaduna sun ile-igbimọ asofin agba wipe, gomina naa wo ile Senato Suleiman Hunkuyi, lai taa lolobo tabi kilọ fun lori igbese to gbe naa.