Tọkọtaya lu ọmọ ni gbanjo fun 400k

Image copyright PUNCH
Àkọlé àwòrán Baba ọmọ ni ajọmọ oun ati iyawo oun ni lati ta ọmọ jojolo naa

Lẹyin iwadi ọse mẹta, ọwọ sinkun awọn ọtẹlẹmuyẹ ba tọkọtaya kan ti wọn ta ọmọbinrin jojolo ti wọn sẹsẹ bi ni ẹgbẹrun lọna irinwo naira, lẹyin wakati diẹ ti wọn bi ọmọ naa.

Awọn tọkọtaya naa, ti oruko wọn n jẹ Ifeanyi ati Emmaculata Elijah, wa lati agbegbe Amakpu nijọba ibile Owerri nipinlẹ Imo, jẹwọ wipẹ awọn ta ọmọ awọn niye owo naa.

Elijah sọ wipe ajọmọ oun ati iyawo oun ni lati ta ọmọ tuntun jojolo naa.

Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, obinrin to ra ọmọ tuntun naa sọ wipe oun san owo naa fawọn tọkọtaya to ta ọmọ wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

Alukoro fun ileesẹ ọlọpa nilu owerri, Andrew Enwerem, nigba to n safihan awọn tọkọtaya naa sọ wipe, awọn ri ọmọ ti wọn ta naa gba pada lọjọ kẹtadinlogun osu yi, ati wipe awọn yoo gbe ọrọ naa lọ sileẹjọ lẹyin tawọn ba ti pari gbogbo ọfintoto to niise pẹlu isẹle naa.

Enwerem fikun wipe awọn si n wa awọn afurasi meji to ni ise pẹlu isẹlẹ naa.