Tunde Bakare: Ọlọrun kìí yan ọ̀lẹ sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ rárá

'Ayé ló bàjẹ́ ti ọmọ olè ń dájọ; oníkálukú mọ ẹ̀tọ́ tó yẹ́'.

Oluṣọagutan Tunde Bakare ṣalaye bi idamẹwaa ṣe bẹrẹ ninu bibeli àti pe kò si ẹni ti wọn gbé ibọn tì pe dandan ni koo san idamẹwaa rara.

O ni iṣẹ́ ọwọ́ òun ni oun n jẹ nitori pe Ọlọrun kìí pe ọ̀lẹ si iṣẹ alufaa.

Bakare àti Buhari pẹlu Ọṣinbajo

Olusọaguntan Bakare sọrọ nipa ijọba Muhammadu Buhari pe ó ti gbiyanju nitori pe èèyàn ni èèyàn yoo maa jẹ laye.

O ni Akoko to fun Buhari lati lọ ki ẹlomii le tẹsiwaju lati ibi ti Buhari ba iṣẹ dé.

Bakan naa lo mẹnuba ajọṣepọ oun ati igbakeji aarẹ Ọṣinbajo pe, Ẹ̀gbá meji kò gbódó ja ara wọn níyàn ni ọrọ awọn.

Iru awọn iroyin ti ẹ le nifẹ̀ si: