Lai Muhammed: Ìjà àgbẹ̀ àti darandaran kìíṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tàbí ẹlẹ́yàmẹ̀yà

Àlhájì Lai Mohammed àti Mínísítà Raji Fashola
Àkọlé àwòrán,

Àlhájì Lai Mohammed àti Mínísítà Raji Fashola

Minisita fun iroyin ati aṣa, Lai Mohammed ti ṣe alaye wipe rogbodiyan to n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran ni awọn apa ibi kan lorilẹede Naijiria ko ni ohunkohun ṣe pẹlu ẹsin tabi ẹlẹyamẹya gẹgẹ bi awọn oloṣelu kan ṣe n pariwo rẹ.

Mohammed sọrọ naa lọjọbọ lasiko to n dahun ibeere nibi akanṣẹ eto apero ijọba apapọ lori ipese awọn ohun elo amayedẹrun nilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Ọyọ.O ṣe alaye wipe a nilo ifọrọwanilẹnuwọ to peye lati le fi idi okodoro ọrọ mulẹ lori ohun to ṣokunfa awọn iṣekupani to n waye ni awọn apa ibi kan lorilẹede yii.

Àkọlé fídíò,

'Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí àwa dìbò fún Buhari'

Mohammed ni awọn ọmọ orilẹede yii fẹran lati maa ti ọwọ ọṣelu, ẹsin ati ẹlẹyamẹya bọ awọn iṣẹlẹ to dede waye boya nipasẹ ayipada oju ọjọ, aito nnkan ohun elo tabi iwa ọdaran.O ni, "Ni ọdun 1960 ti orilẹede yii gba ominira, awọn ọmọ orilẹede Naijiria ko ju bii milliọnu mejilelaadọta lọ.Ṣugbọn lọnii, onka awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti sunmọ igba milliọnu. Omi, ilẹ, ati papa oko ti milliọnu mejilelaadọta eeyan n lo ni ọdun 1960 naa lo si n jẹ lilo nibayii ti onka awọn ọmọ orilẹede wa ti sunmọ igba milliọnu.

Àkọlé àwòrán,

Awọn lọbalọba ko gbẹyin nibi ipade itagbangba naa

Eyi jẹ ọkan lara awọn iredi ti ija fi n waye laarin awọn agbẹ ati darandaran."O tọka si adinku to n de ba omi 'Lake Chad' ti awọn orilẹede mẹfa ọtọọtọ nile adulawọ bii Chad, Central African Republic, Benin Republic, Niger, Cameroon ati Naijiria gbẹkẹ le fun eto ọgbin ati ọsin ẹja gẹgẹ bii ohun mii tohun fa ija laarin awọn agbẹ ati darandafan lati agbegbe naa.

Lati le fi idi ọrọ munlẹ wipe ija awọn agbẹ ati darandaran ko ni ọwọ ẹsin tabi ẹlẹyamẹya ninu, Mohammed fi kun ọrọ rẹ wipe bi igba ti adiẹ n jẹ ifun ara wọn ni ọrọ naa ni awọn apa ibi ti wahala ti n waye.

Àkọlé àwòrán,

Wọn rọ awọn eniyan ẹkun Iwọ oorun Gusu ṣe atilẹyin fun aarẹ Muhammadu Buhari ninu eto idibo ọdun 2019.

Oni, "Ẹmi ti o bọ sọnu ninu wahala awọn to n ji maalu gbe nipinlẹ Zamfara nikan ṣoṣo, o ju apapọ ẹmi ti o bọ sọnu nipinlẹ Taraba, Benue ati Plateau.

Ohun iyalẹnu sini wipe Musulumi ati Fulani n bẹ lara awọn ọdaran to n ji maalu gbe, bẹẹ sini Musulumi ati Fulani n bẹ lara awọn eeyan ti maalu wọn n sọnu."

Àkọlé àwòrán,

Gomina ipinle Ọyọ, Abiọla Ajimọbi ko gbẹyin nibi ipade naa

"Bawo ni awa ṣe le sọ wipe wahala naa ni ọwọ ẹsin tabi ẹlẹyamẹya ninu?""Bi ida meji ninu mẹta awọn eeyan to ri ẹwọn he nipasẹ ija laarin agbe ati darandaran nipinlẹ Kebbi, bẹẹ sini Musulumi ati Fulani n bẹ laarin awọn agbẹ, gẹgẹ bi o ṣe wa laarin awọn darandaran.

Àkọlé àwòrán,

Minisita naa kesi awọn akọroyin ati awọn adari lati dẹkun kikọ ayederu iroyin

Nitori naa, o yẹ ki a dẹkun titọwọ ẹsin ati ẹlẹyamẹwa bọ ọrọ awọn ọdaran tabi awọn oṣẹlẹ to dede waye."Minisita naa kesi awọn akọroyin ati awọn adari lati dẹkun kikọ ayederu iroyin, nitori iru awọn iroyin bẹẹ n yara gba ẹmi awọn eeyan ju ọta ibọn lọ ni awọn agbegbe ti wahala ti n waye.

Àkọlé àwòrán,

Minisita fun irinna, Rotimi Amaechi, Minisita fun nkan alumọni inu omi, Suleiman Adamu

O parọwa si gbogbo ọmọ orilẹede Naijiria lati sa ipa wọn ki wọn si rii daju wipe alafia jọba gẹgẹ bi o ti wa tẹlẹ ri.Lara awọn eeyan pataki ti o pejupesẹ sibi akanṣe eto apero naa ni minisita fun Ohun Amuṣagbara, Iṣẹ Ode, ati Ile Igbe, Babatunde Raji Fashola, Minisita fun Igbokegbodo Ọkọ, Rotimi Amaechi, Minisita fun Alumọni Omi, Onimọ ẹro Suleiman Adamu, ati gomina ipiẹ ỌYỌ, Abiọla Ajimọbi.

Awọn ọba alade, aṣoju ijọba ipinlẹ Ọyọ, oniṣẹ ọwọ, oniṣowo ati bẹẹbẹẹ lọ naa ko gbẹyin nibi akanṣe eto apero naa ti o jẹ Ikẹrinla iruẹ lati ọwọ ijọba apapọ orilẹede yii.

Lai Muhammed: Ọgọrun le mẹwa ni awọn ọmọ to sọnu ni Dapchi

Àkọlé àwòrán,

Lai Muhammed ni awọn ti ba awọn alẹnu lọrọ sọrọ lori ọrọ ọun

Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti kede pe ọgọrun o le mẹwa ni awọn ọmọ ti wọn ko le se isiro fun lẹyin ti ikọlu kan waye ni ile iwe imọ ẹkọ Sanyesi to wa ni Dapchi ni ipinlẹ Yobe.

Awọn ọmọ ọun ni wọn sọ pe wọn fi se awati lẹyin ti awọn kan ti wọn fura si gẹgẹ bi ọmọ ikọ Bokoharam ya wonu ile iwe ọun lọsẹ to kọja.

Ni ọjọ aiku ni awọn asoju ijoba apapọ - ninu eyi ti a ti ri Minisita fun eto iroyin ati asa, ọgbẹni Lai Muhammed ati Minisita fun ọrọ abẹle, Abdulraman Danbasau - se abẹwo si ipinlẹ Yobe lati wadi ofintoto ọrọ ọun.

Nigaba ti o n ba ile ise BBC sọrọ, Minisita fun eto iroyin, Lai Muhammed sọ pe, awọn se ipade pẹlu, Gomina ipinlẹ Yobe, Ibrahim Geidam, awọn alasẹ ile iwe ọun, awọn obi ati awọn osisẹ alaabo.

Oríṣun àwòrán, Yobe State Government

Àkọlé àwòrán,

Eyi jọ ijingbe ti o waye ni Chibok nipinlẹ Borno

Lai Muhammed ni gẹgẹ bi nnkan ti ọga agba ile iwe ọun, Hajia Adama Abdulkareem ati kọmisọna fun eto ẹkọ ni ipinlẹ Yobe, Muhammed Lamin sọ fun awọn, ẹgbẹrun kan din mẹrin ni iye gbogbo ọmọ to wa ni ile iwe yii lọjọ ti isẹlẹ ọun sẹlẹ, sugbọn ti ọgọrun le mẹwa poora niniu awọn ọmọ ọun.

Sugbọn minisita ọun ti fi lede pe, ijọba apapọ ti kona mọ igbiyanju rẹ lati rii daju pe wọn wa awọn ọmọ ọun lawari, wọn si da wọn pada fun awọn obi wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ile iwe Dapchi nwa awọn ọmọbinrin to le lọgọrun

O ni awọn osisẹ alaabo ti musẹ se lori wiwa awọn ọmọ ọun nibikibi ti wọn ba wa, ati pe, ijọba ti pasẹ pe ki ile isẹ ọlọpa ati ile isẹ aabo-ara-ẹni-laabo-ilu fi awọn osisẹ wọn ranse si awọn ile iwe kaakiri ni ipinlẹ Yobe.

Ninu ọrọ tirẹ, Minisita fun ọrọ abẹle, Abdulrahman Danbasau sọ pe, idi ti awọn fi se abẹwo ọun ni lati ridi okodoro ọrọ, ki awọn lee m'ọnu odo t'awọn o dọrunla si.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹ si: