Gomina Ambode buwọlu aba isuna ti o le ni trillionu kan naira

Awọoran Ambode lasiko ti o n tọwọ bọ iwe Image copyright @AkinwumiAmbode
Àkọlé àwòrán Gomina se ileri lati se awọn akanse isẹ tuntun

Owo to le diẹ ni triliọnu kan naira ni ipinlẹ Eko yoo na fun isuna rẹ lọdun 2018.

Gomina ipinlẹ Eko, Akinwumi Ambọde lo buwọlu isuna yii ninu eyi tiẹka isẹ gbogbo ti gba biliọnu mọkanlelaadọjọ naira, eto ọrọ aje ki ọrinlẹrinwo o din meje biliọnu naira.

biliọnu mejilelaadọrun ni wọn ya sọtọ fun ẹka eto ilera, ẹka igbafẹ, asa ati ọrọ ẹsin gba biliọnu mejila abọ naira nigbati eto ẹkọ ko biliọnu mẹrindinlaadoje naira.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán "aba isuna itẹsiwaju ati idagbasoke" ni akori isuna ipin Eko fundun 2018

Labẹ eto isuna yii kan naa, ijọba ipinlẹ Eko ni owo iyasọtọ wa fun pipari awọn gbọngan asa marun, idasilẹ ibudo isẹmbaye kan ni ile aarẹ tẹlẹ ti ijọba apapọ sẹsẹ fa le ipinlẹ Eko lọwọ; ile ikonkan isẹmbaye si nla kan laarin ile aar tẹlẹ ni Marina.

Bakannaa ni wọn tun ya owo sọtọ fun kikọ papa isire si Igbogbo, Epe, Badagry Ajeromi Ifelodun (Ajegunle) pẹlu owo lati pari awọn akanse isẹ to n lọ lọwọ ni Epe ati Badagry Marina.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aato ilu kun ara ohun ti ipin Eko yoo mojuto dun 2018

Pẹlu gbogbo ilakalẹ yii, kọmisọna fun eto isuna ni ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Akinyẹmi Ashade ni ẹẹdẹgbẹrun biliọnu o din mẹta ni owo ti ijọba nreti ati pa wọle si asuwọn rẹ ni ọdun 2018.

O ni wọn yoo lo owo yii lati fi se aayan eto isuna naa, nigbati ijọba yoo ya owo kun un lati rii pe erongba rẹ fun ọdun 2018 jọ

Bakana ni gomina ọhun tun sọ awọn aba meji ọtọọtọ di ofin.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹlẹgbẹ owo ni ipinlẹ Eko ya sọtọ fun ipese ohun amayedẹrun

Ambọde tun buwọlu awọn abadofin meji.

Akọkọ nibẹ ni aba ti o n risi ẹka igbokegbodo ọkọ ati eleyi ti o n se amojuto ẹka eto ekọ.

Ofin ẹka igbokegbodo ọkọ fun ọdun 2018 lo n risi idagbasoke ati isakoso igbokegbodo to muna doko ati ipese awọn ohun elo amayedẹrun nipinlẹ Ẹko.

Ofin naa n se odiwọn ipese igbokegbodo ti owo rẹ ko ga ju ara lọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ireti wa wipe igbesẹ lati se ayipada amojuto igbokegbodo ọkọ nipinle Eko yoo tẹsiwaju lọdun 2018

Ofin naa n se odiwọn ipese igbokegbodo ti owo rẹ ko ga ju ara lọ.

Bakana sini ireti wa wipe igbesẹ naa yo se ayipada amojuto igbokegbodo ọkọ nipinle ọhun.

Ni abala eto ẹko, ofin odun 2018 to n risi ẹka naa yo se atiwaye isakoso eto ẹko pẹlu ifojusun ti o dan maran.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Gomina Ambọde ni Agbekalẹ awọn akanse isẹ tuntun yo kun awọn idagbagbasoke to wanilẹ tẹlẹ

Lasiko ti o n se afihan aba isuna odun 2018 fun ile igbimọ asofin ipinlẹ Ẹko, Gomina Ambode jẹjẹ wipe isejọba oun yo sa gbogbo ipa lati yọri awọn akanse isẹ ti o n lọ lọwọ, pẹlu agbekalẹ awọn akanse isẹ tuntun miran ti yo pakun awọn idagbagbasoke ti o n bẹ lakọsile lati bi i ọdun meji abọ sẹyin.

Gomina Ambode se afikun ọrọ wipe akọle aba isuna ọdun 2018 ni, "aba isuna itẹsiwaju ati idagbasoke".