South Africa: Ramaphosa ti parọ awọn alabasisẹ pọ rẹ

Aworan aarẹ Ramaphosa Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ramaphosa ni igbakeji aarẹ tẹlẹri lorilẹede South Africa

Aarẹ orilẹede South Africa, Cyril Ramaphosa, ti yan igbimọ isejọba tuntun eleyi ti o n safihan yiya ara rẹ kuro ni isejọba aarẹ ana, Jacob Zuma.

Cyril Ramaphosa yan lara awọn eekan ninu ija igbogunti iwa ijẹkujẹ lorilẹede naa sinu igbimọ isejọba rẹ. Amọsa, ọpọ awọn minisita to ni ariwisi lorisirisi ni wọn si wa ninu isejọba rẹ ọ

Aarẹ tuntun fun orilẹ̀ede South Africa yan Nhlanhla Nene si ipo pada gẹgẹ bi i alakoso fun eto isuna, ninu igbesẹ ati da a pada si ẹnu isẹ, lẹyin igba ti aarẹ tẹlẹri, Jacob Zuma yọ ọ o ni'po.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ oselu ANC kan an nipa fun aarẹ tẹlẹ, Jacob Zuma, lati kọwe fi ipo silẹ nibẹrẹ osu keji ọdun 2018, lori ẹsun iwa ibajẹ

Ẹgbẹ oselu ANC kan an nipa fun aarẹ tẹlẹ, Jacob Zuma, lati kọwe fi ipo silẹ nibẹrẹ osu keji ọdun 2018, lori ẹsun iwa ibajẹ.

Ọgbẹni Ramaphosa gba ijọba pẹlu ileri igba ọtun fun orilẹede naa ati ẹjẹ lati gbogun ti iwa ibajẹ.

Ọ fi pupọ ninu awọn alakoso ti aarẹ ana yan si'po sile, sugbọn pupọ ninu awọn alabasisẹ pọ to ku lo padanu ipo wọn.

Igbakeji aarẹ ẹgbẹ oselu African National Congress (ANC) ti o n se ijọba lorilẹede South Africa lọwọ, David Mabuzza ni wọn kede gẹgẹ bi i igbakeji aarẹ orilẹede naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ramaphosa se ileri lati gbogun ti iwa ibajẹ

Aya ọgbẹni Zuma tẹlẹri, Nkosazana Dlamini-Zuma ti Ọgbẹni Ramaphosa fi agba han ninu eto idibo ẹgbẹ oselu ANC to waye ninu osu kejila ọdun 2017, ni wọn yan sipo gẹgẹ bi i minisita fun ile isẹ aarẹ.

Iyansipo ti o gbajumọ julọ ni ti Nhlanhla Nene si ipo eto isuna lẹyin ti wọn ti le e kuro ninu osu kejila odun 2015.

Saaju ni igbesẹ naa se sokunfa ọkan o jọkan ariwisi ati ibẹru laarin awọn oludokowo, bakana sini o mu ki adinku de ba agbara owo Rand, gẹgẹ bi o se ja lolẹ lẹgbẹ Dollar.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ramaphosa gba ijọba lẹyin ti asaaju rẹ fi ipo silẹ ninu igbese ti o mun ọpọlọpọ awuyewuye lọwọ

Ọgbẹni Ramaphosa ti o jẹ oludokowo ẹni ọdun marundinlaadọrin, se ileri, igbogun ti iwa ibajẹ, ibomirin eto ọrọ aje ati ipese isẹ lọpọ yanturu ninu ọrọ akọkọ ti o ba awọn eeyan orilẹede rẹ sọ.

O gba ijọba lẹyin ti asaaju rẹ fi ipo silẹ ninu igbese ti o mun ọpọlọpọ awuyewuye lọwọ.

Isakoso ọdun mẹsan ọgbẹni Zuma koju ọpọlọ ẹsun iwa ibajẹ, lasiko ti orilẹede rẹ n foju wina obitibiti gbese ati airisẹ se.

Wo aarẹ orilẹede South Africa tuntun