Ijamba baalu Syria: Ẹmi ọmọ Russia mejilelọgbọn sọnu

Aworan ọkọ ofurufu An-26- Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Ọkọ ofurufu An-26- bii iru eleyi lo jẹ onipele meji fun kiko awọn ọmọogun ati awọn araalu

O le ni eniyan bii ọgbọn to padanu ẹmi wọn nigbati baalu akero kan to jẹ ti orilẹede Russia jabọ ni Syria.

Ileesẹ ologun Orilẹede Russia lo fidi isẹlẹ yii mulẹ.

Ileesẹ iroyin Russia to gbẹnu sọ fun ileesẹ oloogun ilẹ naa, kede pe ọkọ ofurufu An-26 jabọ nigba to n balẹ ni papako awọn ọmọogun ofurufu to wa ni Latakia, lorilẹede Syria.

Iroyin naa wipe awọn ọmọogun mọ̀kandinlogoji lo padanu ẹmi wọn, eyi to yatọ si iroyin akọkọ to wipe eniyan mejilelọgbọn lo padanu ẹmi wọn.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si:

O fikun pe kii se pe wọn yinbọn mọ ọkọ ofurufu naa, ati wipe akọsilẹ to wa nilẹ saaju isẹlẹ naa fihan wipe o seese ko jẹ wipe baalu naa ni iyọnu lo sokunfa ijamba naa.

Ileesẹ ologun orilẹede Russia naa fikun wipe, iwadi si isẹlẹ naa ti bẹrẹ.