Buhari ti sofin aleekun owo ori ileese ọti ati siga

tobacco Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Minisita fun eto isuna sọ pe orilẹede Naijiria ni wọn ti n gba owo ori to kere julo lori tobacco

Ijọba apappọ orilẹede Naijiria ti mu aleekun ba owo ori ti awọn ile ise to n pon ọti ati awọn ti o n se siga yoo maa san gẹgẹ bi owo ori.

Agbẹnusọ fun Minisita Kemi Adeosun, Oluyinka Akintunde sọ pe, aarẹ Buhari ti fọwọ si abadofin ọun.

Nigba ti o n fi oju ọrọ naa lede, Minisita fun eto isuna, Kemi Adeosun sọ pe, ọjọ kẹrin osu kẹfa ni ofin yii yoo gbera sọ, idi eyi ni lati fun awọn ileesẹ tọ'rọ ọun kan ni anfaani osu mẹta lati gbaradi fun aleekun ọun.

Kẹmi Adeosun ni anfaani meji to wa ninu igbesẹ naa ni pe, yoo se aleekun owo to n wọle sapo ijọba, ati pe, yoo tun mu adinku ba bi awọn eniyan se n mu oti ati siga lọna to lee sakoba fun eto ilera wọn.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ni ọjọ isinmi ni Kẹmi Adeosun foju ọrọ ọun lede

Adeosun tun sọ pe aleekun ọun kii se oun ti yoo ku giri lọ soke, o ni ijọba ti gbe igbesẹ lati rii pe aleekun owo ori yii ko gun awọn ileese tọrọ naa kan lapa, nidi eyi, wọn ti seto ki owo ori ọun maa lekun diẹdiẹ lati asiko yii titi di ọdun 2020.

Aleekun ọun ni wọn sọ pe, yato si siga, yoo de ba ọti beer, waini ati awọn ọti mii laarin ọdun 2018 ati ọdun 2020.

Adeosun wa sọ pe, orilẹede Naijiria lo n gba owo ori to kere ju lọwọ awọn ile isẹ to n pese ọti ati siga.