Ọwọ ọlọpa ti tẹ 'were' to sa ọmọ meji pa nipinlẹ Ogun

Aworan Ada Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Afunrasi alangana naa na papa bora lẹyin to pa awọn ọmọde meji ki ọwọ awọn ọlọpa to tẹẹ

Ọwọ ọlọpa ti tẹ ọkunrin alangana kan to pa ọmọ meji nileewe alakọbẹrẹ kan ni ipinlẹ Ogun.

Alukoro ileesẹ ọlọpa ni ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi lo kede eyi nilu Abẹokuta.

Afunrasi ọdaran naa ti wọn f'orukọ bo laṣiri ṣa dede wọ ileewe alakọbẹrẹ St. John's Anglican nilu Agodo iyẹn ni ijọba ibilẹ Ogun waterside pẹlu ada lasiko isere wọn, to si ṣa awọn ọmọ meji, Mubarak Kalesowo pẹlu Sunday Obituyi pa.

Bi o tilẹ jẹ wi pe afunrasi alangana naa sa lọ ni kete to ṣiṣẹ ibi rẹ tan, ọwọ awọn ọlọpa tẹẹ lagbegbe ileto Agodo.

Ta lo pa Abimbọla ati Mubarak l'Ogun?

Buhari dasi ipaniyan Benue

Soyinka s'ọrọ lori ipaniyan awọn darandaran

Alukoro ileesẹ ọlọpa ni arakunrin naa tun gbiyanju ati sa awọn ọlọpa to fẹ mu u pẹlu ada ki wọn to kapa rẹ pẹlu iranlọwọ awọn ọdẹ agbegbe naa.