Champions league: Messi fi Chelsea gun akasọ ọgọrun goolu

Messi lori papa Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Messi ati Ronaldo ni agbabọọlu meji to si de ibi ami aadọrun goolu ni Champions league

Gbajugbaja agbabọọlu ikọ Barcelona ti orilẹede Spain ni, Lionel Messi ti fi ikọ agbabọọlu Chelsea ti ilẹ Gẹẹsi se akasọ de ibi ami goolu ọgọrun ninu idije champions league.

Ami ayo meji ni Messi gba wọle ninu mẹta si odo ti Barcelona fi na Chelsea.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lẹyin ijakulẹ yii ireti Chelsea ti pin lori idije Champions league saa yii

Bi ọrọ ti ri yii, Chelsea ti jabọ kuro ninu ọkọ idije champions league.

Messi ni yoo se agbabọọlu keji ninu iwe itan idije champions league ti yoo gba ayo ọgọrun sinu awọn ninu lẹyin ti Christano Ronaldo ti kọkọ fi ami yi lelẹ ni saa bọọlu to kọja.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nibayii, awọn ikọ agbabọọlu mẹjọ ti yoo kopa ninu ipele komẹsẹ-o-yọ ẹlẹni mẹjọ ti farahan

Bakannaa ni Bayern Munich na na Bekistas mọle pẹlu ayo mẹta si ẹyọ kan.

Awọn ikọ agbabọọlu to ku bayii ninu ipele komẹsẹ-o-yọ ẹlẹni mẹjọ to ku bayii ni Liverpool, Real Madrid, Manchester city, Juventus, Sevilla, Roma, Barcelona ati Bayern Munich.

Buhari ransẹ ayọ sikọ Naijiria

Peter Cech de ibi aami ifẹsẹwọnsẹ igba

'Ipo kẹrin ko lee rọgbọ fun Chelsea'

Related Topics