Ọlọpa ko lee sọ boya 'were' lọkunrin to sa ọmọ meji pa l'Ogun

Afunrasi ọdaran naa Image copyright Ogun state police command
Àkọlé àwòrán Ileẹjọ ni yoo sọ boya ọlọdẹ ori ni arakunrin to sa ọmọ meji pa nile ẹkọ alakọbẹrẹ kan l'Ogun

Ileesẹ ọlọpa ko ti lee fi idi rẹ mulẹ boya lootọ ni arakunrin to sa awọn ọmọ meji pa ni ipinlẹ ogun jẹ alanganna.

Awọn ileesẹ ọlọpa ni lootọ ọwọ ti tẹ arakunrin afurasi ọdaran naa ti wọn si ti fi oju rẹ faraye ri nilu Abẹokuta, tii se olu ilu ipinlẹ naa l'Ọjọọbọ (Thursday).

Ninu ọrọ to ba BBC sọ, alukoro ileesẹ ọlọpa nipinlẹ ọhun, Abimbọla Oyeyẹmi, ni ko si lọwọ ọlọpa lati se ayẹwo ọpọlọ fun arakunrin naa.

"Arakunrin naa yoo de ile ẹjọ. Nibẹ ni adajọ yoo ti sọ boya ki wọn muu lọ si ileewosan ayẹwo ọpọlọ abi ki wọn fi silẹ."

Nibayii Kọmisọna feto ẹkọ nipinlẹ Ogun ti salaye wi pe ijọba yoo gbe igbesẹ nipasẹ isedajọ rẹ lati rii pe arakunrin naa foju wina ofin.

Ninu ifọrọwerọ rẹ pẹlu BBC, arabinrin Modupẹ Mujọta ni ijọba ipinlẹ naa ti n ṣe "atunto eto abo lawọn ileewe rẹ gbogbo lẹyin isẹlẹ naa.

"Isẹlẹ naa kii se ohun ti a lee pe ni ipenija abo lawọn ileewe wa. Ijamba ti ko dun mọ wa ninu ni. Eto abo to jọju wa lawọn ileewe kan ni ipinlẹ yii sugbọn ijọba ti n gbe igbesẹ lati se atunto ilana eto abo lawọn ileewe gbogbo nipinlẹ yii."

Lọjọ ade ni afunrasi ọdaran yii ṣa dede wọ ileewe alakọbẹrẹ St. John's Anglican nilu Agodo iyẹn ni ijọba ibilẹ Ogun waterside pẹlu ada lasiko isere wọn, to si ṣa awọn ọmọ meji, Mubarak Kalesowo pẹlu Sunday Obituyi pa.

Ọrọ naa se bi ẹni fẹ ba ibomiran yọ nigba ti iroyin tun kan wi pe ọlọdẹ ori ni arakunrin naa ati pe o ni aisan ọpọlọ.

Related Topics