Ondo APC: Àṣà ojú-àwo-làwo fi ń gbọbẹ̀ kò lè wáyé l'Ondo

Ipade L'Ondo

Oríṣun àwòrán, Ondo APC

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú APC tako Oshiomole

Àwọn ọmọ ẹgbẹ òṣèlú All Progressives Congress ní ìpínlẹ̀ Ondo ti tako ààrẹ gbogboogbò fún APC Adams Oshiomole fún àṣẹ lílo àṣà ìdìbò abẹ́nú ojú àwo làwó fí ń gbọbẹ.

Awọn ọmọ ẹgbẹ́ ṣe ìpinnu láti lo ìdìbo àbẹnu láti yan olùdíje sípò gẹ́gẹ́ bii àṣà ẹgbẹ́ tẹ́lẹ̀lẹ́yìn ìpàdé bònkẹ́lẹ́ pàjáwìrì tí àwọn ìgbìmọ amúṣẹ́ ṣe ṣe pẹ̀lú gomìnà ìpínlẹ̀ Ondo Rotimi Akeredolu lónìí.

Oríṣun àwòrán, Ondo APC

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ẹgbẹ́ òsèlú APC tako Oshiomole

Ìpínu àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ìpínlẹ̀ Ondo yìí lòdì sí ìdarí ilé ẹgbẹ l'Abuja tí Adams Oshiomole jẹ́ ààrẹ.

Lẹ́yìn ti abenugan ile ìgbìmọ aṣofin Bamidel Oloyelogun síde ọ̀rọ̀ ní gbogbo ọmọ ẹgbẹ́ fẹnukò pé àwón ò lè lo àbá tuntun yìí nítori pé kò sí ìwé ofin tí o ṣe àtilẹ́yìn fún irú àṣà tuntun yìí

Tayo Alasọadura tó jẹ́ ọmọ ilé ìgbìmọ aṣofin àgbà fún ẹkùn gbùngbùn Ondo tó darí ìpàdé náà sàlàyé pé bótilẹ̀ jẹ pé o wà nínú ìwé òfin lati lo èyí tó bá wù wọn nínú méjèèjì síbẹ̀ àwọn o lé lòó nítori ọ̀rs ààbo à ti pé lílo ìdìbò ojú àwo lawo fí n gbọbẹ̀ yóò dá rògbòdìyàn silẹ̀ láàrín ẹgbẹ

Ondo; 1000 si 2000 naira lowo ori ilẹ fun mẹkunu

Oríṣun àwòrán, Rotimi Akeredolu/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ipinlẹ Ondo fẹ bẹrẹ si gba owo ile ati ilẹ

Igbese ipinlẹ Ondo lati bẹrẹ si ni gba owo ori ilẹ lọwọ awọn ara ilu ni ko ba awọn ara ilu lara mu, ti wọn si fero wọn han lori ọna abayọ si owo ori lawujọ.

Alaga fun ile-isẹ to n risi ọrọ owo to n wọle labẹle ni ipinlẹ Ondo, Tolu Adegbie nigba to n ba BBC sọrọ wipe igbesẹ ijọba ipinlẹ naa ni lati pese ohun amayedẹrun fun awọn ara ilu nipa pipa owo wọle labẹle lọna ti ko ni pa awọn ara ilu lara.

Ọgbẹni Adegbie sọwipe awọn ara ilu kereje yoo san ẹgbẹrun ( 1000) si ẹgbẹwa(2000) naira lọdọọdun gẹgẹbi owo ori ilẹ wọn, nigba ti awon to ba n gbe agbegbe to laju bii Akure to je olu ilu naa, yoo san egbeedogbon(5000) si egbaarun( 10,000) naira, lẹyin ti Gomina Rotimi Akeredolu ba buwọlu atunto ofin naa to ti wa latọdun 2014, ki ọdun yii to pari.

Ninu ọrọ tirẹ, aarẹ awọn ajọ onimọ ijinlẹ ni ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Gboyega Akerele to jẹ onimọ nipa ile kikọ sọwipe ijọba nilo awọn onimọ lati gbe iru igbese yii, nitori ika o dọgba, atiwipe asọ nla kọ ni eniyan nla.

Akerele gba ijọba ni imọran lati pe ipade apaapọ pẹlu awọn ti ọrọ naa kan, ki owo ori ilẹ o ma ba da gbọmi si omi oto, silẹ laarin ijọba ati awọn ara ilu.

Ti a ko ba gbagbe, laipe yii, ni ipinlẹ Eko gbe owo le owo ori ilẹ, eleyii ti awọn eniyan bu ẹnu atẹ lu, to si mu ki ijọba ipinlẹ naa o din iye owo ori ilẹ ku.