Odaran meji jẹwọ wipe Dino Melaye ni ọga wọn

Aworan Dino Melaye Image copyright Twitter/Melaye
Àkọlé àwòrán Sẹnatọ Dino Melaye ni asoju ẹkun idibo Iwọ-oorun Kogi, nile Igbimọ Asofin agba lorilẹede Naijiria

Ajọ Ọlọpa lorilẹede Naijiria ti gbe Sẹnatọ Dino Melaye to n soju ẹkun idibo Iwọ-oorun Kogi lọsi ile ẹjọ, lẹyin ti awọn ọdaran meji jẹwọ wipe Sẹnatọ naa ni awọn n sisẹ fun.

Alukoro Ọga Ọlọpa, Jimoh Moshood to sọ eyi ninu atẹjade, sọwipe awọn ọdaran meji to ni wipe awọn n sisẹ fun Melaye naa ni awọn fi panpẹ ọba gbe lọjọ kọkandinlogun, Osu Kini, Ọdun yii, lẹyin ti wọn kọju ibọn si awọn ọlọpa ni ijoba ipinlẹ Dekina, ni ipinlẹ Kogi.

Moshood sọwipe awọn ti gbe ẹjọ naa ka ile-ẹjọ to kalẹ si Lọkọja, ni ipinlẹ Kogi nibi ti wọn ti fẹsun kan Melaye ati awọn mẹta miran wipe wọn n lo ohun ija oloro lọna aitọ.

Arakunrin naa sọwipe awọn ọdaran jẹwo wipe awọn ti ji ọpọlọpọ eniyan gbe lagbeegbe naa, atiwipe awọn n sisẹ fun awọn oloselu lawujọ.

Alukoro ajọ ọlọpa naa wa fikun wipe Sẹnatọ Dino Melaye ti awọn fi ẹsun ọdaran kan, ati Ọkunrin kan ti orukọ re n jẹ Mohammed Audu, ni awọn ko i ti foju ri lati igba ti awọn ọdaran meji naa ti jẹwọ fun awọn ọlọpa.