Dino Melaye: Ko si ohun ti oro ejo lee se fun alabahun.

Aworan Senato Dino Melaye Image copyright TWITTER/DINO MELAYE
Àkọlé àwòrán Ile ise olopaa fẹsun kan Senato Dino Melaye niwaju ile ẹjo giga kan ni Lokoja

Sẹnatọ Dino Melaye to n soju ẹkun idibo iwọ oorun Kogi ti fesi si ẹsun pe o lẹdi apo pọ lati huwa ọdaran.

Eyi waye lẹyin ti ileesẹ ọlọpa Naijiria gbe lọ si ile ẹjọ pe awọn ọdaran meji jẹwọ pe oun ni Baba isalẹ awọn.

Melaye kede ọrọ naa loju opo twita re. O ni ''Pabo ni irọ ti ijọba ipinlẹ Kogi ati ile isẹ ọlọpa n pa mo mi yoo ja si. Ase lasan ni. Ọgbon ati dun mọhuru mọhuru mọ mi ni.''

Lọjọ aje ni agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpa, Moshood Jimoh, se afihan awọn afurasi meji kan nilu Lokoja to ni wọn jẹwọ pe Senato Dino Melaye lo ran awọn nisẹ lati wu iwa janduku nipinlẹ Kogi.

Saaju igba naa, Dino Melaye ti fesi sọrọ ọga ọlọpa lori aṣẹ to pa pe ki gbogbo awọn ọlọpa to n ṣiṣẹ ẹṣọ lọdọ awọn eeyan pataki lawujọ, to fi mọ awọn oloṣelu ati awọn to di ipo iṣakoso mu jakejado orilẹẹde Naijiria kuro lẹyin wọn ni kiakia.

O ti to ọjọ mẹta ti Dino Melaye ati gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello ti n sọko ọrọ si ara wọn.