Ibo gomina Ondo: Akeredolu fidirẹmi nileẹjọ

Rotimi Akeredola Image copyright ONDO STATE GOVERNMENT
Àkọlé àwòrán Akeredolu ati Abraham ni wọn jọ figagbaga fun asia ẹgbẹ oselu APC fun ipo gomina ipinlẹ Ondo lọdun 2016

Ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria ti da ẹjọ kotẹmilọrun ti gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu gbe wa siwaju rẹ nu pẹlu alaye pe ko lẹsẹ-n-lẹ.

Olusẹgun Abraham, to baa du ipo asia gomina ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ondo, lo n pee lẹjọ.

Rotimi Akeredolu tọ ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lọ, lati lodi si idajọ ti ileẹjọ giga ilu Abuja gbe kalẹ, ti ileẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja kannaa si faramọ, ninu idajọ to gbe kalẹ losu keje ọdun 2017 lati gba Olusẹgun Abraham laaye, lati fun Akeredolu ni iwe ipẹjọ lori ẹjọ to pe gomina ipinlẹ Ondo naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Akeredolu ati Abraham ni wọn jọ figagbaga fun asia ẹgbẹ oselu APC fun ipo gomina ipinlẹ Ondo lọdun 2016

Ọgbẹni Abraham npẹ ẹjọ lori idibo abẹle ninu ẹgbẹ oselu APC, eleyi to fa Rotimi Akeredolu kalẹ gẹgẹbii oludije fun ipo gomina, lasiko idibo gomina nipinlẹ naa to waye kẹyin.

Gbogbo awọn adajọ maraarun lo panupọ gbe idajọ naa kalẹ

Ninu idajọ gbogbo wa lo fọwọsi, ti wọn gbe kalẹ, igbimọ onidajọ ẹlẹni marun ileẹjọ naa gbe idajọ kalẹ wipe, ẹjọ kotẹmilọrun ti Gomina Akeredolu pe ko lẹsẹ nlẹ.

Bakannaa ni ileẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria, tun pasẹ pe ki Akeredolu san ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (N500, 000) gẹgẹbii owo 'gba maa binu' fun Abraham.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: