Akẹkọ Dapchi: Buhari pinnu lati se awari ọmọ kan to ku

Aworan awọn akẹkọ Dapchi Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ipenija nla ni dida akẹkọ kan sooso to ku pada wale layọ ati alafia jẹ fun ijọba Naijiria

Aarẹ orilẹẹde Naijiria, Muhammadu Buhari ni ijọba oun yoo sa ipa gbogbo lati mu akẹkọbinrin Dapchi kan to sẹku lahamọ awọn ikọ agbebọn Boko Haram pada wale.

Ninu ọrọ kan to fi lede lori oju opo Twitter re,o bọkan je lori bi Boko Haram ti se mu akẹkọ naa sọdọ.

Leah Sharibu ni akẹkọ kan to sẹku laarin awọn ọmọ obirin ile ekọ Dapchi ti awọn ikọ Boko Harm jiigbe ti wọn si da pada lọjọọru.

Wọn ni Boko Haram kọ lati fi ọmọbinrin naa silẹ nitori pe o kọ lati yi ẹsin rẹ pada kuro ni ẹsin Kristẹni si Musulumi.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọbinrin Dapchi: Mi o lọ sile iwe mọ

Ninu atẹjade kan ti agbẹnuso fun aarẹ orilẹede Naijiria, ọgbẹni Garba Shehu fi sọwọ si awọn oniroyin, o ni, ''Ko ru Aarẹ Buhari loju pe ojuse rẹ ni lati daabo bo gbogbo ọmọ orilẹẹde Naijiria lai fi tẹsin tabi ẹya se.''

O tẹsiwaju pe, ''Aarẹ jẹ ko di mimọ pe awọn to jẹ musulumi ododo kii fipa muni lati s'ẹsin wọn.''

Loni lo yẹ ki Aarẹ Buhari se ipade nile ijọba l'Abuja pẹlu awọn akẹkọ Dapchi naa ti Boko haram da pada.

Awọn iroyin ti ẹ lee nifẹẹ si: